07/08/2025
*YORÙBÁ PÓJÚ-OWÓ*
Ariwo ńlá la fi ń pàdé àlejò ńlá.
Ajá tó bá rorò, la fi ń dẹ isà ejò.
Bi àlè ìyá ẹni bá ti ju Bàbá ẹni lọ, Baba la máa ń pe irú wọn...
Bí aṣọ bá tóbi, òòlù ló máa ń lùú.
Bí Egúngún bá só, Atọ́kùn ló máa ń gbọ́ òórùn rẹ̀.
Ọgbọ́n ló máa ń pẹ́ kó tó ranni,
Páápààpá ni wèrè ń rànnìyàn.
Àti kékeré ni Alábahun ti máa ń kó ọmọ rẹ̀ sínú pósí.
Àti ìgbà ìwásẹ̀ ni ìgbín tí máa ń kó ọmọ rẹ̀ sínú kònjò.
Àti kékeré ni àrígiṣẹ́gi tí máa ń sé ara rẹ̀ mọ́nú igi.
Fúnra kúlúsọ ló ń gbẹ́ sàréè ara rẹ̀..
Òjò tẸ́yẹ Ẹ̀lúùlú fẹnu pè,
Orí ara rẹ̀ náà ló rọ̀ sì pátá
Ilé tẸ́yẹ ẹ̀gà fẹnu kọ́, ẹnu ara rẹ̀ náà ló tún fi bìí wó lulẹ̀
A kò ní í fi ọwọ́ ara wa ṣe ara wa.
Ikú àìtọ́jọ́ kò níí pa àwa àti mọ̀lẹ́bi wa
Ọjọ́ òní yóò jẹ́ ọjọ́ rere fún wa ..