
08/10/2025
Wòlíì Daniel Abodunrin àti ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ ní Ilé àwọn ẹranko (Zoo) ní ọdún 1991
Ní ọdún 1991, Arákùnrin Daniel Abodunrin tí ó pe ara rẹ̀ ní wòlíì Ọlọ́run gbìyànjú láti ṣe asínjẹ ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì tí Dáníẹ́lì nínú ihò.
Ìsẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ ní inú ọgbà Fáṣítì ilẹ̀ Ìbàdàn nínú ilé ẹranko tí ó wà níbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn ni ó máa ń lọ láti lo ìsinmi láti wòran níbẹ̀.
Ó wọ asọ tí ó sì fi okùn Pupa sọ ara rẹ̀ pẹ̀lú Bíbélì lọ́wọ́. Ó wọ ìyára àwọn kìnnìún lọ. Ó ṣàlàyé pé òun náà fẹ́ fi hàn pé bí Ọlọ́run ṣe kó Dáníẹ́lì yọ nínú Bíbélì kúrò nínú ihò kìnnìún, Ọlọ́run yóò kó òun yọ pẹ̀lú.
Àmọ́ sá, fún ìyàlẹ́nu, omi tẹ̀yìnbọ̀gbínlẹ́nu mọ́ wòlíì Daniel Abodunrin lọ́wọ́. Àwọn kìnnìún kọjú ìjà sí sì í, Wọ́n fa Daniel Abodunrin tí ó pe ara rẹ̀ ní wòlíì Ọlọ́run pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
Gbogbo orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni òkìkí ikú wòlíì yìí kàn tí Ìsẹ̀lẹ̀ yìí sì gbalẹ̀ kiri.
Ǹjẹ́ a rí ẹni tí ó rántí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí?