07/06/2025
*ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ TI KRISTI NI NIGERIA ATI ÒKÈ OKUN.*
*Ẹ̀KỌ́ ILE Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.*
*ÀKÒRÍ GBÒÒRÒ*
*MIMURA ÀWỌN ÈNÌYÀN ỌLỌ́RUN SILẸ ÌṢÀKÓSO/ṢÍṢE OLÓRÍ*
JUNE 8 2025
Ọjọ Isinmi Pentikọsti
*ẸKỌ 21*
*ISỌRI 3: IMURASILẸ FÚN ÌṢÀKÓSO NÍNÚ MAJẸMU LÁÉLÁÉ (II)*
*Akori*
ỌLỌ́RUN MURA ÀWỌN WOLII MAJẸMU LAELAE SILẸ FUN ÌṢÀKÓSO (I)
*AKỌSORI*
O si wí fun wọn pé, "Ẹyin ti oye kò yé, ti o sì yigbi ni aya lati gba gbogbo eyi ti àwọn wolii ti wí gbọ!" (Luku 24:25).
Ọlọ́run máa n ró awọn ti a pè lagbara, On kó àwọn olórí bii Isaiah ati Jeremiah nípasẹ̀6 àwọn àdánwò ati iṣiyèméjì lati mu eto àtọ̀runwá Rẹ ṣẹ.
*ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ*
Lẹyin ti Jésù ti ku, àwọn ọrẹ meji rin lo si ìletò kan ti a n pe ni Emmausi. Ni ọna, wọn pàdé Jesu, Eni ti O jíǹde kúrò nínú oku, bi o o tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ko kọ́kọ́ da A mọ. Wọn nỉ ibanujẹ wọn si daamu, ṣùgbọ́n Jésù n rin pẹ̀lú wọn, O'si n ṣàlàyé Iwe Mimọ fun wọn. O ba wọn wi fun aini oye wọn. Eyin fihan pé Ọlọ́run ṣetan lati ran wa lọ́wọ́ ni àwọn àkókò to le ṣùgbọ́n aini ìgbàgbọ́ wa ati aini àwòrán nla naa (Ọlọ́run) le mu nnkan buru sii. Ni ọjọ Isinmi pentikosti ti ọdun yii, a ranti lati tẹtisi ìtọ́ni Ọlọ́run nípasẹ̀ Ẹmi Rẹ, gẹgẹ bi Luku 24:25. Itan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yii n kọ wa ki a máṣe kọ awọn ìtọ́ni Ọlọ́run silẹ. A gbọ́dọ̀ maa tẹti si Ọrọ Rẹ ki a si maa tẹle ibi ti O ba dari wa si. Ẹ jẹ ki a gba iranwo Ọlọ́run ki a si gbẹkẹle ọgbọ́n Rẹ. Nigba ti a ba gbọ́ràn si I, a le bori ibẹru ati iruju.
*ÀṢÀRÒ LATI INU BÍBÉLÌ*
*Mon. 2:* Esikiẹli Tọ Awọn Eniyan Naa Sọ́nà (Esek. 12:8)
*Tue. 3:* Esikiẹli Ṣamulo Ọrọ Ọlọ́run Pẹlu Ìgbọràn (Esek. 12:8-9)
*Wed. 4:* Itọni Esikiẹli Jẹ Ami (Esek. 12:10-11)
*Thur. 5:* Esikiẹli Gbọran Gẹgẹ Bi Atọna Awọn Eniyan Naa (Esek. 12:7)
*Fri. 6:* Akọlu Si Aláìgbọràn (Esek. 12:13)
*Sat. 7:* Ifọwọsowọpọ Oniwa-Bi-Ọlọ́run Nìkan Lo N Ṣàṣeyọrí (Esek. 12:14).
*ÀṢÀRÒ FUN ÌFỌKÀNSÌN*
1. Awọn olori oníwà-bí-Ọlọ́run ti wọn ní àfojúsùn síbẹ̀ lori títọ awọn ènìyàn ni ọna Ọlọ́run, ifẹ Rẹ ati ọrọ Rẹ ni a máa n fi oore-ọ̀fẹ́ Rẹ bò, ti a si maa n ro lágbára.
2. Awọn olori oníwà-bí-Ọlọ́run, ti wọn fara wọn jì fun títọ awọn ènìyàn sọ́nà gẹ́gẹ́ bi ọna Ọlọ́run, ni a maa n tipàsẹ oore-ọ̀fẹ́ Rẹ ró lagbara ati daabo bo. Àfojúsùn wọn lori ìfẹ́ Ọlọ́run maa n fa atilẹyin ati iro-lagbara atọrunwa. Igbe aye Isaiah ati Jeremiah ṣàpẹẹrẹ eyi.
*ẸSẸ BIBELI FUN IPILẸ Ẹ̀KỌ́: Sekariah 1:1-6*
*ILEPA ATI ÀWỌN ERONGBA*
*ILEPA:* Lati ṣagbekalẹ pe titẹle Ọlọ́run tọkàntọkàn n fun wa loore-ọ̀fẹ́ lati tẹti si ìtọ́ni Rẹ nípasẹ̀ àwọn olori ti a ti yan.
*ÀWỌN ERONGBA:* Ni opin ẹ̀kọ́ yii, a n reti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lati le ṣafihan lati inu:
i. àwọn iriri Isaiah, bi Ọlọ́run ti múra àwọn eniyan Rẹ silẹ fun ìṣàkóso, ati
ii. àwọn iriri Jeremiah, bi Ọlọ́run tì ró àwọn ènìyàn Rẹ lágbára fún ìṣàkóso.
*IFAARA*
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: Isaiah 6:1swj; Jeremiah 1;4-10.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fun ẹ̀kọ́ ti o kọja, nibi ti a tí kọ nipa bi Ọlọ́run ṣe mura Esra ati ati Nehemiah silẹ lati dari àwọn ènìyàn Rẹ nínú imubọsipo, nipa tara ati nipa tẹmi. A ri bi Ọlọ́run Ẹni ti n tọju ẹni jinlẹjinlẹ, ṣe lo àwọn ọkùnrin ọlọgbọn inu, bii Esra ati Nehemiah lati ko àwọn eniyan Rẹ padabọ lati wa mọ ati ni oye Ọrọ Rẹ. Wọn ṣeranwo lati mu àwọn ènìyàn Jerúsálẹ́mù bọsipo ati lati ṣe atúnkọ awọn odi rẹ, pẹ̀lú àwọn ènìyàn naa ti wọn tẹti silẹ ati ti wọn si gbọ́ràn.
Ẹ̀kọ́ ti òní "ỌLỌ́RUN MÚRA ÀWỌN WÒLÍÌ MAJẸMU LAELAE SILẸ FÚN ÌṢÀKÓSO (I)," yoo ran wa lọwọ lati ri bi Ọlọ́run ti kilọ, ṣe imubọsipo ati bi O ti gba awọn ènìyàn Rẹ la nípasẹ̀ àwọn wolii ti O yan. Àwọn wolii yii dari, ṣatọna, wọn si tọ àwọn ọmọ Ọlọ́run pada sínú ìfẹ́ ati oore-ọ̀fẹ́ Rẹ. Ọlọ́run ko le dẹkùn ati maa dari ati ṣatọna àwọn ènìyàn Rẹ láéláé, eyi ti ìṣe idi ti O fi fun wa n Ẹmi Rẹ, Ẹmi Mimọ, lati tẹsiwaju fifi ọna Olúwa han wa. Lonii, bi a ti n ranti Pentikosti, ẹ jẹ ki a gbẹkẹle pé Ẹ̀mí Ọlọ́run yoo maa wa pẹ̀lú wa nígbà gbogbo. Amin.
*KÓKÓ Ẹ̀KỌ́*
*I. IMURASILẸ ISAIAH*
*II. IMURASILẸ JEREMIAH*
*ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́*
I IMURASILẸ ISAIAH (Isa. 6:1SWJ)
O si fi kan mi ni enu, o si wí pé: "kiyesi I, eyi ti kan ete rę, a mu aişedeede rę kuro, a si fọ cạẹ rẹ nu (ẹsẹ 7).
a. Ẹsẹ 1: Ibapade Isaiah pẹ̀lú Ọlọ́run Mímọ́ laarin ijó-ajorẹyin nipa tẹmi labẹ akoso oba Ussiah ṣafihan titobi julọ Ọlọ́run lori ọrọ eniyan, o ṣi Isaiah niye nipa ipa rẹ ninu eto àtọ̀runwá Ọlọ́run.
b. Ẹsẹ 1-4: Ìran rẹ nipa ti ọlanla Ọlọ́run ati iwa mímọ Rẹ ni ipa to jinlẹ lori rẹ, eyi ti o fa bibọwọ fun Ọlọ́run ati nini oye iwa Rẹ. O tun n ṣalaye pàtàkì jíjẹwọ ẹṣẹ ẹni ati ìrònúpìwàdà (wo ẹsẹ 5; O. Daf. 99:9).
d. Ẹsẹ 5: Ijẹwọ awọn ẹṣẹ rẹ lọ́nà irẹlẹ níwájú Ọlọ́run fihàn pé o ṣetán fún ìṣẹ́ wolii rẹ (wo O.D. 51:3; Lk. 5:8).
e. Ẹsẹ 6,7: Iwẹnumọ rẹ nípasẹ̀ ẹṣẹ - iná n ṣàpẹẹrẹ isọdi-mimọ rẹ fun Ìṣẹ́ wolii (wo Lef. 8:15; I Pet. 1:22).
ẹ. Ẹsẹ 8: Ìdáhùn rẹ lẹ́sẹẹsẹ, "Emi ni in; ran mi," si ìpè Ọlọ́run n jẹrisi ṣíṣetan latọkanwa rẹ lati sin, bii Samueli (I Sam. 3:4) ati Anania (Ise 9:10).
f. Ẹsẹ 9swj: Nini Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gẹgẹ bi o ti wa nínú àbùdá meji ti ìgbàlà ati ìdájọ́ (Heb. 4:12; 2 Kor. 2:15-16), ro o lagbara lati fi òtítọ́ jẹ́ ìṣẹ́ Rẹ.
g. Dájúdájú, Isaiah sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nínú ìṣotito Rẹ lati pèsè rẹ silẹ fun ìṣẹ́ ti sísọ ọkàn Ọlọ́run fun awọn ènìyàn Rẹ. Eyi pèsè agbára fún un ati ìpinnu fún ìṣẹ́ olórí ti wolii.
*II IMURASILẸ JEREMIAH* (Jer. 1:4-10) Ki Emi ki o to da ọ ni inu, Emi ti mọ ọ, ki iwọ ki o si to ti inu jáde wa ni Emi ti sọọ di mímọ, Emi O si ya o sọtọ lati jẹ wolii fun àwọn orílẹ̀ èdè (ẹsẹ 5).
a. Ẹsẹ 4-5: Ọ̀rọ̀ Oluwa tọ Jeremiah wa, o fihan pé a ti yan an a si ti ya a sọtọ fun ipa wolii rẹ, koda ṣáájú ibi rẹ. Eyi n ṣafihan ọgbọ́n Ọlọ́run ati imọtẹlẹ Rẹ ni yiyan an. O ti wa ninu ọkan Ọlọ́run saaju ki a to bi o rara.
b. Ẹsẹ 6: Jeremiah gẹgẹ bi Mose ati awọn ẹda inu Bíbélì miran, ṣafihan irẹlẹ o si ri ara rẹ bi alaiyẹ nigba ti Ọlọrun pe e, o fi biba Ọlọ́run sowọ-pọ nitootọ han (Ekso. 3:11-12; Onidj. 6:15).
d. Ẹsẹ 6-8: O fa sẹ́yìn, o si ṣé alaída ara rẹ lójú, ṣugbọn Ọlọ́run tun fi da a lójú niti ìwàláàyè àti atilẹyin Rẹ. Eyi laaye ara rẹ ṣe iranwọ pupọ lati ro Jeremiah lagbara fun ìṣe ìṣàkóso ti wòlíì.
e. Ẹsẹ 9: Ọlọ́run ró Jeremiah ni agbara nipa fifọwọ ba ẹnu rẹ, ti n ṣàpẹẹrẹ àṣẹ àtọ̀runwá, eyi si fun un lagbara lati maa sọ Ọrọ Ọlọ́run pẹ̀lú agbara (Ekso. 4:11-12; Isa. 6:7).
ẹ. Ẹsẹ 10: Ọlọ́run ti múra Jeremiah silẹ pẹ̀lú ìṣẹ́ ìránṣẹ́ wolii alabuda meji niti fifa ẹṣẹ ati aiwa-bi-Ọlọ́run tu pẹlu gbigbe iwa òdodo ati ìgbọràn ró (Esek. 33:7-9; Ise 20:20-21), idi àṣeyọrí ìṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ ni yii laarin àwọn ènìyàn Ọlọ́run.
f. Ọlọ́run ṣafihan títóbi julọ Rẹ ati itọju Rẹ ni mimura ìránṣẹ́ to jẹ ààyò Rẹ, Jeremiah silẹ ati títọ o, fún ìṣàkóso ti wòlíì. Ṣe on jọ̀wọ́ ara rẹ fun Ọlọ́run fún imurasilẹ Rẹ (wo Isa. 6:1-8; Ìṣe 9:15-16)?
*ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TI A RÍ KỌ*
1. Ọlọ́run ko ni àwọn ènìyàn nikan, ṣùgbọ́n O tun ni àwọn ìranṣẹ ti O pè, O n tọ ọba wọn lati maa dari àwọn miran bo ti tọ.
2. Ọlọ́run n pè, ṣe imurasilẹ fun, bẹẹ nỉ O n rán awọn agbẹnusọ Rẹ niṣe. Ṣi ọkan rẹ paya ki o si jẹ ki Ọlọ́run ba ọ sọrọ.
*ÀWỌN ÌBÉÈRÈ*
1. Ǹjẹ́ àwọn olori wa ti wọn jẹ wolii n ṣatọna awọn eniyan daradara gẹgẹ bi ìrètí Ọlọ́run lode oni bi? Bi ko ba ri bẹẹ, kin ni àwọn ìmọ̀ràn ti o ni fun àtúnṣe?
2. Ṣe o gbagbọ pe àwọn eniyan kan wa ti Ọlọ́run ko le lo lati dari àwọn ènìyàn Rẹ, lonii?
*ÀWỌN ÌDÁHÙN TI A DABAA FUN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ*
*ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ 1*
i. Àwọn olori ti wọn jẹ wolii gbọdọ maa gbé/ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú òtítọ́
ii. Wọn gbọdọ maa dari pẹ̀lú ibọwọ fún Ọlọ́run
iii. Ijọwọ ara ẹni fun ìtọ́ni Ẹmi Mimọ ṣe pàtàkì
iv. Wọn gbọdọ kọ iwa ọkanjua, ojúkòkòrò ati imọ tara-ẹni-nìkan silẹ
v. Ọkàn aanu ṣe pàtàkì, wọn ko gbọ́dọ̀ di kun ajaga awọn eniyan
vi. Iwa irẹlẹ ṣe koko, wọn gbọdọ borí igberaga
vii. Ọrọ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ irinṣẹ wọn àkọ́kọ́ fún ìṣàkóso
viii. Wọn gbọdọ yago fun ṣíṣe ilara ẹ̀bùn ati iṣẹ-ìránṣẹ́ àwọn miran
ix. Wọn gbọdọ maa ṣíṣẹ pẹ̀lú ìgbóná-ọkàn, ki wọn fi ọkan si pe wọn yóò ṣe isiro lọ́jọ́ ọla
x. Gbígbé ìgbé ayé òdodo ati yiyago fun ẹṣẹ pọndandan.
*IDAHUN SI ÌBÉÈRÈ 2* Ọlọ́run ṣi n wa àwọn ènìyàn ti yoo lo fún erongba ayérayé Rẹ: O máa n lo àwọn ti wọn:
a. Ti di ẹni ìgbàlà ati atunbi.
b. Ti di ẹni isọdọtun.
d. Fẹ lati yọnda ara wọn.
e. Timúrasilẹ (Esra 7:10).
c. Ti mura tan ni ọkan ati ni ẹmi.
f. Ti gba irolagbara.
ÀMÚLÒ FUN ÌGBÉ AYÉ ẸNI
Jesu, Olu alufa ati Wolii wa, ṣe àṣeparí ohun gbogbo ti o ṣe pataki fun imubọsipo ènìyàn pada si ọdọ Ọlọ́run lẹyin ìṣubú nínú Ọgbà Édẹ́nì, O di àlàfo ti n bẹ laarin eniyan ati Ọlọ́run. Pẹ̀lú gbogbo ijiya, iku ati àjíǹde Rẹ, ènìyàn ṣi n gbe nínú ẹṣẹ síbẹ̀. Síbẹ̀, ninu ìfẹ́ ati aanu Rẹ, Ọlọ́run n tẹsiwaju lati maa ran àwọn wolii wá lati maa rán àwọn eniyan Rẹ leti ati lati tọ wọn pada sọ́dọ̀ ara Rẹ. Ṣiwaju sii, ni ọjọ́ Pentikosti, O fun wa ni Ẹmi Mimọ fun agbara lati kéde ihinrere ati lati fa àwọn miran wa sọ́dọ̀ Rẹ. Eyi ṣi jẹ ìṣẹ́ fún gbogbo Kristẹni òde-òní síbẹ̀.
*IGUNLẸ*
Ifẹ Ọlọ́run ko lopin o si jẹ ti laelae/àìnípẹ̀kun. On ṣàfẹ́rí àwọn olori ti wọn faraji si títọ àwọn ènìyàn sínú oye to jinlẹ nipa Rẹ ati si Ọrọ Rẹ, ati àwọn to mura tan lati dari àwọn ti wọn ti ṣako lọ pada sọdọ Rẹ pẹlu òtítọ́ àti ọkàn mímọ. Ṣé o ṣetan fun Ìṣẹ́yii bi?
*ÀKÍYÈSÍ*