RCCG Yorùbá Manuals.

RCCG Yorùbá Manuals. Oluṣọ_Aguntan E. A Adeboye ẹni tí Ọlọ́run n gba ọwọ rẹ kọ ̀RUN_ṢIṢI

📖📖 *ÌWÉ Ọ̀RUN_ṢÍṢÍ, ÌTỌ́NI OJOJUMỌ FÚN IDAPỌ TIMỌTIMỌ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN.* -ỌJỌ́ ÀBÁMẸ́TA , ỌJỌ́ KEJIDÍNLỌ́GBỌ̀N, OSÙ KẸRIN, ...
18/04/2026

📖📖 *ÌWÉ Ọ̀RUN_ṢÍṢÍ, ÌTỌ́NI OJOJUMỌ FÚN IDAPỌ TIMỌTIMỌ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN.*
-
ỌJỌ́ ÀBÁMẸ́TA , ỌJỌ́ KEJIDÍNLỌ́GBỌ̀N, OSÙ KẸRIN, *ODÚN 2026*
-
*ÀKỌLÉ: YÍYÍ ÌDÈ PADÀ (REVERSING BO***GE)*
-
*AKỌSÓRÍ*
> "Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi, nítorí tí Ó ti fòróró yàn mí láti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì; Ó ti rán mi láti wo àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn sàn, láti kéde ìdáǹdè fún àwọn òǹdè, àti mímú ìríran padà fún àwọn afọ́jú, láti dá àwọn tí a pa lára sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́," – **Lúkù 4:18**
>
*BÍBÉLÌ KÍKÀ: LÚKÙ 13:10-16*
*10.* Ó sì ń kọ́ni nínú ọ̀kan nínú àwọn sínágọ́gù ní ọjọ́ ìsinmi.
*11.* Sì kíyèsí i, obìnrin kan wà nibẹ̀ tí ó ní ẹ̀mí àìsàn fún ọdún méjì-dín-lógún, ó sì tẹ̀ tan, kò sì lè gbé ara rẹ̀ sókè rárá.
**12.** Nígbà tí Jésù rí i, Ó pè é sọ́dọ̀ Rẹ̀, Ó sì wí fún un pé, "Obìnrin, a tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú àìsàn rẹ."
**13.** Ó sì gbé ọwọ́ Rẹ̀ lé e: lójúkan náà ó sì nàró, ó sì yin Ọlọ́run lógo.
**14.** Olórí sínágọ́gù náà sì bínú jọjọ, nítorí tí Jésù múni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, "Ọjọ́ mẹ́fà ni ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́: nínú wọn ni kí ẹ máa wá láti gba ìwòsàn, kò sì í ṣe ní ọjọ́ ìsinmi."
**15.** Olúwa sì dá a lóhùn, Ó wí pé, "Ìwọ àgàbàgebè, olúkúlùkù yín ha kì í tú màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kúrò nínú ibùjẹ láti fà á lọ mu omi ní ọjọ́ ìsinmi?"
**16.** "Obìnrin yìí, tí í ṣe ọmọ Ábrahámú, tí Èṣù sì ti dè, kíyèsí i, fún ọdún méjì-dín-lógún, kò ha yẹ kí a tú u kúrò nínú ìdè yìí ní ọjọ́ ìsinmi?"
-
*ÀLÀYÉ Ẹ̀KỌ́ (MESSAGE):*
Nígbàkígbà tí Ọlọ́run bá fẹ́ yí ohun tí kò lè yí padà padà, Ó máa ń tẹ̀lé ìlànà kan, èyí tí ó sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpàdé àmúdájú látọ̀run (divine appointment). Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé Yóò ṣètò lọ́nà ìyanu fún àwọn ènìyàn láti pàdé ara wọn.
Inú ọmọkùnrin kan wà nígbà kan rí, ó ti di ọmọ ọdún àádọ́ta (50) kò sì ní aya, nítorí pé kò lè ṣí ẹnu sọ fún obìnrin pé, "Ǹjẹ́ o le fẹ́ mi?" Ọ̀tá dè é tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ tí kò fi lè ṣí ẹnu sọ̀rọ̀ fún eyikeyìí obìnrin tó bá wù ú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kàwé gidi. Ó mọ̀ pé òun ní ìṣòro, ṣùgbọ́n kò mọ bí òun yóò ṣe lè rí òmìnira. Ó jẹ́ oríire fún un pé Ọlọ́run pàṣẹ fún wa láti ṣe ètò kan ní ìlú rẹ̀. Nínú ètò náà, ó fún ayé rẹ̀ fún Jésù Kristi. Kì í ṣe pé Jésù gba ọkàn rẹ̀ nìkan ni, ṣùgbọ́n Ó fọ́ àjàgà ayé rẹ̀, lẹ́yìn oṣù mẹ́fà, ó gbéyàwó. Oṣù mẹ́sàn-án lẹ́yìn ìgbéyàwó rẹ̀, aya rẹ̀ bí ìbejì. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, ó tún bí ìbejì mìíràn. Ìtàn ọkùnrin yìí jẹ́ ẹ̀rí pé kò sí ìdè kankan tó lágbára jù fún Ọlọ́run láti fọ́.

Mo gbàdúrà fún ọ lónìí pé eyikeyìí àjàgà tó bá ń yọ ọ́ lẹ́nu yóò di fífọ́ tìtu-tìtu, ní orúkọ Jésù.

Nínú Bíbélì kíkà òní, Jésù lọ sí sínágọ́gù gẹ́gẹ́ bí ìṣe Rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ní ọjọ́ pàtó yìí, Ó pàdé obìnrin kan tí Èṣù ti dè fún ọdún méjì-dín-lógún (18). Ó tẹ̀ tan tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi lè nàró. Fún ọdún méjì-dín-lógún gbáko, ó wà nínú ìhámọ́ nínú gbogbo abala ayé rẹ̀.
Láìbìkítà bí ìdè rẹ̀ ti burú tó, ó pàdé Jésù ní sínágọ́gù, ó sì rí òmìnira rẹ̀ gbà. Àjàgà ìdè tó ti dè é fún ìgbà pípẹ́ di fífọ́, ó sì rí àǹfààní láti gbé orí àti ọwọ́ rẹ̀ sókè láti yin Olúwa.
-
Àìsáyà 10:27 sọ pé, "Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, tí a óò mú ẹrù rẹ̀ kúrò ní èjìká rẹ, àti àjàgà rẹ̀ kúrò ní ọrùn rẹ, a óò sì fọ́ àjàgà náà nítorí òróró náà."
Nítorí náà, mo pàṣẹ ní orúkọ tó ga ju gbogbo orúkọ lọ, pé ohunkóhun tó bá ń dí ọ lọ́wọ́ láti gbé orí rẹ sókè, Ọlọ́run yóò jẹ́ kí o ní ìpàdé àmúdájú kan tí yóò da ọ́ nídè pátápátá lọ́wọ́ ohunkóhun tó bá ti dè ọ́ mọ́lẹ̀, ní orúkọ Jésù.
-
*KÓKÓ ÀDÚRÁ:*
Baba, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n ní ìpàdé pẹ̀lú Rẹ tí yóò fọ́ eyikeyìí irúfẹ́ ìdè tó bá wà nínú ayé mi, ní orúkọ Jésù.
-
*ONKỌ̀WÉ: PASTOR E. A. ADEBOYE*
-
*BÍBÉLÌ NÍ ỌDÚN KAN: 2 ÀWỌN ỌBA 1-3*
-
*ORIN ÌYÌN:*
*Ma koja mi Olugbala*
-
Pass me not o gentle Savior
-
1. Ma koja mi, Olugbala,
Gbo adura mi,
'Gba t'Iwo ba n p'elomiran,
Mase koja mi!

CHORUS
Jesu! Jesu! Gbo adura mi!
Gba t'Iwo ba n p'elomiran,
Mase koja mi.

2. N'ite anu je k'emi ri,
Itura didun;
Teduntedun ni mo wole,
Jo ran mi lowo.

3. N'igbekele itoye Re,
L'em' o w'oju Re;
Wo 'banuje okan mi san,
F'ife Re gba mi.

4. 'Wo orisun itunu mi,
Ju 'ye fun mi lo;
Tani mo ni l'ayé l'orun
Bikose Iwo?

📖📖 *ÌWÉ Ọ̀RUN_ṢÍṢÍ, ÌTỌ́NI OJOJUMỌ FÚN IDAPỌ TIMỌTIMỌ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN.* -ỌJỌ́ ẸTÌ, ỌJỌ́ KẸTÀDÍNLÓGÚN, OSÙ KẸRIN, *ODÚN 202...
18/04/2026

📖📖 *ÌWÉ Ọ̀RUN_ṢÍṢÍ, ÌTỌ́NI OJOJUMỌ FÚN IDAPỌ TIMỌTIMỌ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN.*
-
ỌJỌ́ ẸTÌ, ỌJỌ́ KẸTÀDÍNLÓGÚN, OSÙ KẸRIN, *ODÚN 2026*
-
*ÀKỌLÉ: YÍYÍ ÀÌLÉSO PADÀ*
-
*AKỌSÓRÍ*
> "O mu àgan obinrin gbe inu ile, lati ma ṣe oninu-didùn iya awọn ọmọ. Ẹ ma yìn Oluwa!." – **Sáàmù 113:9**
>
**BÍBÉLÌ KÍKÀ: 2 ÀWỌN ỌBA 4:8-17**
**8.** Ó sì ṣe ní ọjọ́ kan, Èlíṣà kọjá lọ sí Ṣúnẹ́mù, níbi tí obìnrin ọlọ́lá kan gbé wà; ó sì rọ̀ ọ́ láti jẹun. Ó sì rí bẹ́ẹ̀, nígbàkúgbà tí ó bá ń kọjá lọ, a máa yà síbẹ̀ láti jẹun.
-
*9.* Ó sì wí fún ọkọ rẹ̀ pé, "Kíyèsí i nísinsìnyí, mo mọ̀ pé ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run ni ẹni yìí tí ó ń kọjá lọ lọ́dọ̀ wa nígbà gbogbo."
-
*10.* "Mo bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí a kọ̀ yàrá kékeré kan sí orí ògiri; kí a sì gbé ibùsùn kan sínú rẹ̀ fún un, àti tábìlì kan, àti àpótí ìjókòó kan, àti ọ̀pá fìtílà kan: yóò sì ṣe, nígbà tí ó bá wá sọ́dọ̀ wa, yóò máa yà síbẹ̀."
-
**11.** Ó sì ṣe ní ọjọ́ kan, ó wá síbẹ̀, ó sì yà sínú yàrá náà, ó sì dùbúlẹ̀ níbẹ̀.
-
**12.** Ó sì wí fún Gẹhásì ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, "Pe obìnrin ará Ṣúnẹ́mù yìí." Nígbà tí ó sì pè é, ó dúró níwájú rẹ̀.
-
*13.* Ó sì wí fún un pé, "Sọ fún mi nísinsìnyí, 'Kíyèsí i, ìwọ ti ń ṣe àníyàn fún wa pẹ̀lú gbogbo ìtọ́jú yìí; kí ni a óò ṣe fún ọ? Ìwọ ha fẹ́ kí a sọ̀rọ̀ rẹ fún ọba, tàbí fún balógun ogun?'" Ó sì dáhùn pé, "Mo ń gbé láàrin àwọn ènìyàn mi."
-
*14.* Ó sì wí pé, "Kí ni a óò ha ṣe fún un?" Gẹhásì sì dáhùn pé, "Lótìítọ́ kò ní ọmọ, ọkọ rẹ̀ sì ti gbó."
-
*15.* Ó sì wí pé, "Pe é." Nígbà tí ó sì pè é, ó dúró ní ẹnu-ọ̀nà.
-
*16.* Ó sì wí pé, "Ní ìwòyí ọdún tí ń bọ̀, gẹ́gẹ́ bí àsìkò ìyè, ìwọ yóò gbe ọmọkùnrin kan mọ́ra." Ó sì wí pé, "Rárá, olúwa mi, ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, má ṣe tan ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ jẹ."
-
*17.** Obìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan ní àsìkò náà tí Èlíṣà ti sọ fún un, gẹ́gẹ́ bí àsìkò ìyè.
-
*ÀLÀYÉ Ẹ̀KỌ́*
Lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, obìnrin kan tó ń dúró de Olúwa fún ọmọ máa ń lọ sọ́dọ̀ Olusoaguntan rẹ̀ fún àdúrà. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, olùṣọ́-àgùntàn náà sọ pé, "Mo ti gbàdúrà fún ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n ń wá ọmọ, nísinsìnyí, wọ́n ti ní ọmọ wọn. Kí ló dé tí tìrẹ fi yàtọ̀?" Obìnrin náà wá sọ̀rọ̀ síta pé òun ti gbìyànjú láti ṣẹ́ oyún kan rí, ṣùgbọ́n iṣẹ́-abẹ náà kò lọ dẹ́ẹ́rẹ́, láti lè gba ẹ̀mí òun là, àwọn oníṣègùn yọ ilé-ọmọ òun kúrò. Nígbà tí olùṣọ́-àgùntàn náà gbọ́ èyí, ó béèrè pẹ̀lú ìyàlẹ́nu pé, "O kò ní ilé-ọmọ láti gbogbo ìgbà yìí, síbẹ̀ o ń ní kí n máa gbàdúrà fún ọ láti bí ọmọ?" Láti ọjọ́ yẹn lọ, olùṣọ́-àgùntàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fún un.
-
Nígbà tí ó ṣàkíyèsí èyí, ó yí padà sí Ọlọ́run, ó sì sọ pé, "N kò ní lọ sọ́dọ̀ olùṣọ́-àgùntàn mi mọ́. Èmi yóò tọ̀ Ọ́ wá, Ìwọ Ẹlẹ́dàá mi." Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ó lá àlá kan lógànjọ́ òru. Nínú àlá náà, ó wà ní ìhòòhò, bí ó ṣe dúró sí ibì kan, ọkùnrin ńlá kan tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú awọ ẹran lọ́wọ́ rẹ̀. Bí ó ṣe dé ibi tí ó dúró sí, ó fi awọ ẹran náà yí ikùn rẹ̀ ká, ó sì pòó mọ́ra. Ìrírí yẹn ni ó jẹ́ òpin àìléso rẹ̀. Ìgbà tí mo gbọ́ nípa rẹ̀ kẹhin, ó ti bí ọmọ márùn-ún!
-
Ọlọ́run lè yí ohun tí kò lè yí padà padà. Nínú Jẹ́nẹ́sísì 21:1-2, Ó yí ipò ikú ara Ábrahámú àti Sárà padà, Ó sì fún wọn ní ọmọ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún àìléso. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nínú 1 Sámúẹ́lì 1:4-20, Ó rántí Hánà, Ó sì ṣí ilé-ọmọ rẹ̀.
Nínú Bíbélì kíkà òní, obìnrin ará Ṣúnẹ́mù rí i pé Èlíṣà ń kọjá lọ, ó sì rọ̀ ọ́ láti wá sínú ilé rẹ̀ láti jẹun. Ó bọ́ ọ ní ọ̀pọ̀ ìgbà mìíràn, ó sì kọ yàrá kékeré kan sínú ilé rẹ̀ láti gbà á lálejò nígbàkúgbà tí ó bá ń kọjá lọ. Nígbà tí Ọlọ́run pinnu láti bẹ̀ ẹ́ wò, Èlíṣà sọ fún un pé yóò bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ fún un pé kí ó má ṣe tàn án jẹ.
Àmì àìgbàgbọ́ kedere ni ìyẹn, ṣùgbọ́n Olódùmárè kọjá orí ìṣiyèméjì rẹ̀, Ó sì fún un ní ọmọkùnrin kan nítorí ọkàn ìsìn rẹ̀.
-
Olùfẹ́, ǹjẹ́ o ń retí iṣẹ́ ìyanu ọmọ tàbí ìléso nínú apá kan ayé rẹ? Máa bá iṣẹ́ ìsìn Olúwa lọ, kí o sì máa bọ̀wọ̀ fún Un. Di ọ̀rọ̀ Rẹ̀ mú ṣinṣin, ojú kò ní tì ọ́ láéláé. Mo gbàdúrà pé Yóò yí gbogbo irúfẹ́ àìléso padà nínú ayé rẹ, Yóò sì mú kí o máa so èso nínú gbogbo apá ayé rẹ, ní orúkọ Jésù.
-
*KÓKÓ ÀDÚRÁ:*
Baba, jọ̀wọ́ sọ mí di ẹni tí ń so èso nínú gbogbo apá ayé mi.
-
**ONKỌ̀WÉ: PASTOR E. A. ADEBOYE**
-
OGBUFỌ : OLÙṢỌ́ ÀGÙNTÀN AYORINDE JOHN JEGEDE @09075527515
-
**BÍBÉLÌ NÍ ỌDÚN KAN: 1 ÀWỌN ỌBA 21-22**
-
*ORIN ÌYÌN: BO TI DUN LATI GBA JESU
- December 07, 2013
Louisa M. R. Stead, c. 1850-1917
Bo ti dun lati gba Jesu
Gbo gege bi oro Re
Ka simi lor'ileri Re
Sa gbagbo l'Oluwa wi

Jesu, Jesu, emi gbagbo
Mo gbekele n'gbagbogbo
Jesu, Jesu, Alabukun
Ki nle gbekele O si

Bo ti dun lati gba Jesu
Ka gbeje wenumo Re
Igbagbo ni ki a fi bo
Sin'eje 'wenumo na

Bo ti dun lati gba Jesu
Ki nk'ara ese sile
Ki ngb'ayo, iye, isimi
Lati odo Jesu mi

Mo yo mo gb'eke mi le O
Jesu mi, Alabukun
Mo mo pe o wa pelu mi
'N'toju mi t**i d'opin.

📖📖 *ÌWÉ Ọ̀RUN_ṢÍṢÍ, ÌTỌ́NI OJOJUMỌ FÚN IDAPỌ TIMỌTIMỌ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN.* -ỌJỌ́ BỌ̀ , ỌJỌ́ KẸRINDINLOGUN, OSÙ KẸRIN, *ODÚN 2...
16/04/2026

📖📖 *ÌWÉ Ọ̀RUN_ṢÍṢÍ, ÌTỌ́NI OJOJUMỌ FÚN IDAPỌ TIMỌTIMỌ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN.*
-
ỌJỌ́ BỌ̀ , ỌJỌ́ KẸRINDINLOGUN, OSÙ KẸRIN, *ODÚN 2026*
-
*ÀKỌLÉ: YÍYÍ ÈGÚN PADÀ*
-
*AKỌSÓRÍ:*
> "Kristi ti rà wá padà kúrò nínú ègún òfin, ẹni tí a ṣe ní ègún fún wa: nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé, 'Ègbé ni fún ẹnikẹ́ni tí a gbé kọ́ sórí igi':" – *Gálátíà 3:13*
>
*BÍBÉLÌ KÍKÀ: 2 ÀWỌN ỌBA 2:19-22*
-
*19.* Àwọn ènìyàn ìlú náà sì wí fún Èlíṣà pé, "Kíyèsí i, mo bẹ̀ ọ́, ipò ìlú yìí dára, gẹ́gẹ́ bí olúwa mi ti rí i: ṣùgbọ́n omi rẹ̀ koro, ilẹ̀ rẹ̀ sì ṣa."
-
*20.** Ó sì wí pé, "Ẹ mú àwokòtò tuntun kan wá fún mi, kí ẹ sì fi iyọ̀ sínú rẹ̀." Wọ́n sì mú un wá fún un.
-
**21.** Ó sì jáde lọ sí ibi ìsun omi náà, ó sì ju iyọ̀ náà sí ibẹ̀, ó sì wí pé, "Báyìí ni Olúwa wí, 'Èmi ti wo omi wọ̀nyí sàn; kì yóò tún sí ikú tàbí ilẹ̀ gbígbẹ (àìlè-so-èso) láti ibẹ̀ mọ́.'"
-
**22.** Bẹ́ẹ̀ ni awo omi náà sàn títí di ọjọ́ òní, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Èlíṣà sọ.
-
*ÀLÀYÉ Ẹ̀KỌ́:*
Nínú Bíbélì kíkà òní, àwọn ọkùnrin ìlú Jẹ́ríkò tọ Èlíṣà lọ láti sọ fún un nípa àwọn ìṣòro tó wà nínú ìlú wọn. Ìlú náà ní ìṣòro nítorí pé Jóṣúà ti fi ègún lé e (Jóṣúà 6:26), ẹni tí ó ti kú láti ọjọ́ pípẹ́. Lẹ́yìn ikú rẹ̀, ègún náà ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú agbára títí tí Èlíṣà fi dé tí ó sì bá a jà láti gbòǹgbò. Láìbìkítà bí ègún ti lágbára tó, Ọlọ́run ní agbára láti yí i padà kí Ó sì sọ ọ́ di ìbùkún.
-
Nínú Jẹ́nẹ́sísì 49:5-7, Jákọ́bù wà lórí ibùsùn ikú rẹ̀ nígbà tí ó ṣépè fún Símónì àti Léfì. Ó ní wọn yóò fọ́nká nínú Ísírẹ́lì.
Ṣùgbọ́n, nínú Nọ́ńbà 3:11-13, Olódùmárè sọ fún Mósè pé, "Mo ti pinnu nínú ọlá-àṣẹ Mi láti mú Léfì jẹ́ àpẹ́rẹ́ àkọ́bí Mi." Nínú ọlá-àṣẹ Rẹ̀, Ọlọ́run yí ègún Jákọ́bù padà lórí Léfì, Ó sì sọ ọ́ di ọlá.
-
Nígbà tí ènìyàn bá wà lábẹ́ ègún, ẹni náà á bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìṣòro, ìyà, ìrora, àìsàn, òṣì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èṣù á máa ṣiṣẹ́ lọ́fẹ̀ẹ́ nínú ayé ẹnikẹ́ni tó bá wà lábẹ́ ègún. Èyí ni ó fà á tí ó fi jẹ́ pé, bí o bá ṣàkíyèsí pé ègún kan ń ṣiṣẹ́ nínú ayé tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ, má ṣe dákẹ́ rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, kígbe sí Olúwa kí o sì gbẹ́kẹ̀lé agbára Rẹ̀ láti dá ọ nídè pátápátá. Ó ń fẹ́ láti gbà ọ́ lọ́wọ́ ohunkóhun tó lè dí ọ lọ́wọ́ láti rìn nínú ẹkùnrẹ́rẹ́ ètò àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún ayé rẹ. Jésù Kristi ti rà ọ́ padà kúrò nínú ègún òfin, gẹ́gẹ́ bí o ti rí i nínú ẹsẹ akọsórí òní. Ó lè yi eyikeyìí ègún tí ẹnikẹ́ni bá fi lé ọ lórí pada, kó sì yí àwọn ègún ìrandiran padà di àwọn ìbùkún ìrandiran.
-
Nínú (1 Kíróníkà 4:9-10), Bíbélì sọ pé Jábẹ́sì jẹ́ ẹni-iyì ju àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n, nítorí ọ̀rọ̀ òdì tí ìyá rẹ̀ sọ mọ́ ọn, a sọ ọ́ di ẹni tí ń fa ìbànújẹ́. Ọ̀rọ̀ ìyá rẹ̀ di ìdènà lórí ayé rẹ̀, èyí sì ni ó sún un láti kígbe sí Olúwa pé, "Áà! Ìbá ṣe pé Ìwọ yóò bùkún mi nítòótọ́, kí Ìwọ yóò sì mú agbègbè mi di ńlá, kí ọwọ́ Rẹ kí ó sì wà pẹ̀lú mi, kí Ìwọ kí ó sì pa mi mọ́ kúrò nínú ibi, kí ó má baà bà mi nínú jẹ́!" Ọlọ́run sì fún un ní ìbéèrè rẹ̀, Ó sì yí ègún tó wà lórí rẹ̀ padà.
-
Olùfẹ́, bí o bá wà lábẹ́ ègún ìran tàbí ti òbí bíi ti Jábẹ́sì, mo fẹ́ kí o kígbe sí Ọlọ́run láti gbà ọ́ lónìí. Òun nìkan ni Ẹni tó lè yí ohun tí kò lè yí padà padà. Sá tọ̀ Ọ́ lọ lónìí, ìwọ yóò sì rí ìdáǹdè kúnkùn gbà.
-
*KÓKÓ*
Ọlọ́run lè mú eyikeyìí ègún tó bá wà nínú ayé rẹ kúrò, kó sì fi ìbùkún Rẹ̀ tí ó kún fún àkúnwọ́sílẹ̀ rọ̀pò rẹ̀.
-
**ONKỌ̀WÉ: PASTOR E. A. ADEBOYE**
-
AYAN OGBUFỌ: OLÙṢỌ́ ÀGÙNTÀN AYORINDE JOHN JEGEDE @09075527515
-
**BÍBÉLÌ NÍ ỌDÚN KAN: 1 ÀWỌN ỌBA 19-20**
-
*ORIN ÌYÌN: JÉSÙ FẸ́ MI, MO MỌ̀ BẸ́È (JESUS LOVES ME, THIS I KNOW)*
-
1. Jésù fẹ́ mi, mo mọ̀ bẹ́ẹ̀,
Bíbélì l’ó sọ bẹ́ẹ̀ fún mi;
Àwọn ọmọdé jẹ́ Tirẹ̀,
Wọ́n jẹ́ tìrẹ̀, Ó lágbára.
**ÈGBÈ:**
*Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù fẹ́ mi!*
*Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù fẹ́ mi!*
*Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù fẹ́ mi!*
*Bíbélì l’ó sọ bẹ́ẹ̀.*
2. Jésù fẹ́ mi, Ẹni tó kú,
Láti ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run;
Y’ó wẹ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù pátá,
K’ọ́mọ kékeré Rẹ̀ wọlé.
3. Jésù fẹ́ mi, mo mọ̀ bẹ́ẹ̀,
Bí Ó ti nífẹ̀ẹ́ rí lát’ijọ́;
Ó gbé ọmọ s’órí eúnkún,
Ó ní, "Ẹ jẹ́ kí wọn wá."

📖📖 *ÌWÉ Ọ̀RUN_ṢÍṢÍ, ÌTỌ́NI OJOJUMỌ FÚN IDAPỌ TIMỌTIMỌ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN.* -ỌJỌ́ RÚ , ỌJỌ́ KARUNDINLOGUN, OSÙ KẸRIN, *ODÚN 20...
16/04/2026

📖📖 *ÌWÉ Ọ̀RUN_ṢÍṢÍ, ÌTỌ́NI OJOJUMỌ FÚN IDAPỌ TIMỌTIMỌ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN.*
-
ỌJỌ́ RÚ , ỌJỌ́ KARUNDINLOGUN, OSÙ KẸRIN, *ODÚN 2026*
-
*ÀKỌLÉ: YÍYÍ IKÚ PADÀ*
-
*AKỌSÓRÍ*
> "Njẹ nitoriti awọn ọmọ jẹ alabapin ara ati ẹjẹ, on pẹlu bẹ̃ gẹgẹ jẹ alabapin ninu rẹ̀; ki o le ti ipa ikú pa ẹni ti o ni agbara ikú run, eyini ni, Èṣu;" – *Hébérù 2:14*
-
*BÍBÉLÌ KÍKÀ: LÚKÙ 7:11-17*
**11.** Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì, Ó lọ sí ìlú kan tí a ń pè ní Náínì; ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ sì bá A lọ, àti ọ̀pọ̀ ènìyàn.
-
*12.* Nígbà tí Ó sì súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ìlú náà, kíyèsí i, a gbé òkú kan jáde, ọmọ kan ṣoṣo fún ìyá rẹ̀, opó sì ni ìyá rẹ̀: ọ̀pọ̀ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.
-
*13.* Nígbà tí Olúwa sì rí i, Ó kẹ́dùn rẹ̀, Ó sì wí fún un pé, "Má sọkún."
-
*14.* Ó sì lọ, Ó fi ọwọ́ kan àpótí òkú náà: àwọn tí ó gbé e sì dúró jẹ́ẹ́. Ó sì wí pé, "Ọmọkùnrin, Mo wí fún ọ, Dìde."
-
*15.* Ẹni tí ó ti kú náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í jókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fọhùn. Ó sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.
-
*16.* Ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn: wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, wọ́n ń wí pé, "Wòlíì ńlá kan dìde láàrin wa;" àti pé, "Ọlọ́run ti bẹ àwọn ènìyàn Rẹ̀ wò."
-
*17.* Ìròyìn Rẹ̀ yìí sì tán ká gbogbo Jùdíà, àti ká gbogbo agbègbè tí ó yí i ká.
-
*ÀLÀYÉ Ẹ̀KỌ́ :*
Lánàá, mo sọ̀rọ̀ lórí bí Ọlọ́run ṣe lè dá àwọn òfin ìṣẹ̀dá dúró tàbí kí Ó yí wọn padà láti ṣe iṣẹ́ ìyanu. Ọlọ́run Olódùmárè lè lo òfin tó ga ju àwọn òfin kan lọ láti borí wọn.
-
Fún àpẹẹrẹ, bí adájọ́ ilé-ẹjọ́ to kéréjú (magistrate) bá dá ẹ̀bi fún ènìyàn kan, tí ẹni náà bá sì lọ sí ilé-ẹjọ́ gíga (high court), adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga lè sọ pé adájọ́ àkọ́kọ́ ṣe àṣìṣe nínú ìdájọ́ rẹ̀, kó sì fagile ìdájọ́ náà. Ọlọ́run ni aláṣẹ tó ga jù lọ ní ọ̀run àti láyé, Ó sì lè borí eyikeyìí òfin ìṣẹ̀dá, títí kan òfin ikú.
-
> "Nígbà tí Ó sì ti sọ bẹ́ẹ̀ tán, Ó kígbe lóhùn rara pé, 'Lásárù, jáde wá.' Ẹni tí ó ti kú náà sì jáde wá, tí a fi ọ̀já òkú dì í lọ́wọ́ àti lẹ́sẹ̀: a sì fi aṣọ-ìpékùn dì í ní ojú. Jésù wí fún wọn pé, 'Ẹ tú u, kí ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ.'" – **Jòhánù 11:43-44*
-
Nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ òkè yìí, Lásárù ti wà nínú ibojì fún ọjọ́ mẹ́rin, gẹ́gẹ́ bí òfin ikú, ó yẹ kí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í jẹrà, kó sì máa rùn. Ṣùgbọ́n, Jésù lo òfin tó ga ju ìyẹn lọ—òfin àjínǹde àti ìyè—láti borí òfin ikú àti ìjẹrà nípa sísọ pé, "Lásárù, jáde wá!" Lójúkan náà tí Ó fúnni ní àṣẹ yẹn, ẹni tó ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin padà sí ìyè. Ọlọ́run Olódùmárè lè yí agbara àti ipa ikú padà.
-
Nígbà tí ènìyàn bá kú tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹrà, ẹ̀jẹ̀ ẹni náà á dudu, awọ ara rẹ̀ á sì bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ̀nù. Láti mú kí Lásárù jíǹde, ó túmọ̀ sí pé ẹran-ara rẹ̀ tó ń jẹrà àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó ti dudu gbọ́dọ̀ padà sí ipò wọn tòótọ́. Òfin àjínǹde àti ìyè borí òfin ikú àti ìjẹrà. Mo gbàdúrà pé òfin àjínǹde àti ìyè yóò borí, yóò borí ohunkóhun tí ikú bá ti ti ọwọ bọ̀ nínú ayé rẹ, mọ̀lẹ́bí, àti iṣẹ́ rẹ, ní orúkọ Jésù.
-
Nínú Bíbélì kíkà òní, opó kan sọ ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo nù sọwọ ikú. Ó ti kọ́kọ́ sọ ọkọ rẹ̀ nù, nísinsìnyí, ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo tún dùbúlẹ̀ láìní èémí, wọ́n sì fẹ́ lọ sin ín. Ó wà nínú ìbànújẹ́ ńlá, ṣùgbọ́n nígbà tí Àjínǹde àti Ìyè dé sí ibẹ̀, Ó yí ìbànújẹ́ rẹ̀ padà sí ayọ̀. Òun tó yẹ kí ó jẹ́ ẹni-ìyọ́nú nínú ìlú nítorí àdánù rẹ̀, ó di ẹni-iyì nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.
-
Olùfẹ́, mo gbàdúrà fún ọ lónìí pé Bàbá mi yóò yí gbogbo ipò tó ti kú tó ti nípa lórí rẹ sí ibi padà di ohun ayọ̀ àti ayẹyẹ, ní orúkọ Jésù.
-
*KÓKÓ ÌRÒSÍ:*
Òfin ikú ń sọ agbára rẹ̀ nù nígbà tí Àjínǹde àti Ìyè bá dé sí ibẹ̀.
-
*ONKỌ̀WÉ: PASTOR E. A. ADEBOYE*
-
*BÍBÉLÌ NÍ ỌDÚN KAN: 1 ÀWỌN ỌBA 16-18*
-
OLUKỌWE : PASTOR E.A ADEBOYE
-
AYAK OGBUFỌ: OLÙṢỌ́ ÀGÙNTÀN AYORINDE JOHN JEGEDE @09075527515
-
*ORIN ÌYÌN:*
ONISEGUN NLA WA NIHIN
Onisegun nla wa nihin
Jesu abanidaro
Oro Re mu ni l'ara da
Agbo ohu ti Jesu

Chorus
Iro didun lorin Seraf
Oruko didun n'nu enia
Orin t'o dun julo ni
Jesu, Jesu, Jesu

A fi gbogb' ese re ji o
A gbo ohun ti Jesu
Rin lo s'orun l'alafia
Si ba Jesu de ade

Gbogb' ogo fun Krist' t'o jinde
Mo gbagbo nisisiyi
Mo f'oruko Olugbala
Mo fe oruko Jesu

Oruko Re l'eru mi lo
Ko si oruko miran
B' okan mi ti nfe lati gbo
Oruko Re 'yebiye

Arakunrin e ba mi yin
A yin oruko Jesu
Arabirin, gb'ohun s'oke
A yin oruko Jesu

Omode at'agbalagba
T'o fe oruko Jesu
Le gba 'pe 'fe nisisiyi
Lati sise fun Jesu

16/04/2026

📖📖 *ÌWÉ Ọ̀RUN_ṢÍṢÍ, ÌTỌ́NI OJOJUMỌ FÚN IDAPỌ TIMỌTIMỌ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN.*
-
ỌJỌ́ RÚ , ỌJỌ́ KARUNDINLOGUN, OSÙ KẸRIN, *ODÚN 2026*
-
*ÀKỌLÉ: YÍYÍ IKÚ PADÀ*
-
*AKỌSÓRÍ*
> "Njẹ nitoriti awọn ọmọ jẹ alabapin ara ati ẹjẹ, on pẹlu bẹ̃ gẹgẹ jẹ alabapin ninu rẹ̀; ki o le ti ipa ikú pa ẹni ti o ni agbara ikú run, eyini ni, Èṣu;" – *Hébérù 2:14*
-
*BÍBÉLÌ KÍKÀ: LÚKÙ 7:11-17*
**11.** Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì, Ó lọ sí ìlú kan tí a ń pè ní Náínì; ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ sì bá A lọ, àti ọ̀pọ̀ ènìyàn.
-
*12.* Nígbà tí Ó sì súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ìlú náà, kíyèsí i, a gbé òkú kan jáde, ọmọ kan ṣoṣo fún ìyá rẹ̀, opó sì ni ìyá rẹ̀: ọ̀pọ̀ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.
-
*13.* Nígbà tí Olúwa sì rí i, Ó kẹ́dùn rẹ̀, Ó sì wí fún un pé, "Má sọkún."
-
*14.* Ó sì lọ, Ó fi ọwọ́ kan àpótí òkú náà: àwọn tí ó gbé e sì dúró jẹ́ẹ́. Ó sì wí pé, "Ọmọkùnrin, Mo wí fún ọ, Dìde."
-
*15.* Ẹni tí ó ti kú náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í jókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fọhùn. Ó sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.
-
*16.* Ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn: wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, wọ́n ń wí pé, "Wòlíì ńlá kan dìde láàrin wa;" àti pé, "Ọlọ́run ti bẹ àwọn ènìyàn Rẹ̀ wò."
-
*17.* Ìròyìn Rẹ̀ yìí sì tán ká gbogbo Jùdíà, àti ká gbogbo agbègbè tí ó yí i ká.
-
*ÀLÀYÉ Ẹ̀KỌ́ :*
Lánàá, mo sọ̀rọ̀ lórí bí Ọlọ́run ṣe lè dá àwọn òfin ìṣẹ̀dá dúró tàbí kí Ó yí wọn padà láti ṣe iṣẹ́ ìyanu. Ọlọ́run Olódùmárè lè lo òfin tó ga ju àwọn òfin kan lọ láti borí wọn.
-
Fún àpẹẹrẹ, bí adájọ́ ilé-ẹjọ́ to kéréjú (magistrate) bá dá ẹ̀bi fún ènìyàn kan, tí ẹni náà bá sì lọ sí ilé-ẹjọ́ gíga (high court), adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga lè sọ pé adájọ́ àkọ́kọ́ ṣe àṣìṣe nínú ìdájọ́ rẹ̀, kó sì fagile ìdájọ́ náà. Ọlọ́run ni aláṣẹ tó ga jù lọ ní ọ̀run àti láyé, Ó sì lè borí eyikeyìí òfin ìṣẹ̀dá, títí kan òfin ikú.
-
> "Nígbà tí Ó sì ti sọ bẹ́ẹ̀ tán, Ó kígbe lóhùn rara pé, 'Lásárù, jáde wá.' Ẹni tí ó ti kú náà sì jáde wá, tí a fi ọ̀já òkú dì í lọ́wọ́ àti lẹ́sẹ̀: a sì fi aṣọ-ìpékùn dì í ní ojú. Jésù wí fún wọn pé, 'Ẹ tú u, kí ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ.'" – **Jòhánù 11:43-44*
-
Nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ òkè yìí, Lá

13/04/2026

📖📖 *ÌWÉ Ọ̀RUN_ṢÍṢÍ, ÌTỌ́NI OJOJUMỌ FÚN IDAPỌ TIMỌTIMỌ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN.*
-
ỌJỌ́ AJÉ , ỌJỌ́ KẸTÀLÁ , OSÙ KẸRIN, *ODÚN 2026*
-
ÀKỌLÉ: YÍYÍ ÀWỌN ÀNÌFÀÀNÍ PADÀ
-
​AKỌSÓRÍ
​"Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò yí ìgbèkùn rẹ padà, yóò sì ṣàánú fún ọ, yóò sì padà wá kó o jọ láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, síbi tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti fọ́ ọ ká sí." – Dibutéronómì 30:3
-
​BÍBÉLÌ KÍKÀ: JÒHÁNÙ 21:15-19
​15. Nígbà tí wọ́n sì jẹun tán, Jésù wí fún Símónì Pétérù pé, "Símónì, ọmọ Jónà, ìwọ ha fẹ́ Mi ju ìwọ̀nyí lọ?" Ó wí fún Un pé, "Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa; Ìwọ mọ̀ pé mo fẹ́ Ọ." Ó wí fún un pé, "Bọ́ àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn Mi."
16. Ó tún wí fún un nígbà kejì pé, "Símónì, ọmọ Jónà, ìwọ ha fẹ́ Mi?" Ó wí fún Un pé, "Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa; Ìwọ mọ̀ pé mo fẹ́ Ọ." Ó wí fún un pé, "Bọ́ àwọn àgùntàn Mi."
17. Ó wí fún un nígbà kẹta pé, "Símónì, ọmọ Jónà, ìwọ ha fẹ́ Mi?" Inú Pétérù sì bà jẹ́ nítorí tí Ó wí fún un nígbà kẹta pé, "Ìwọ ha fẹ́ Mi?" Ó sì wí fún Un pé, "Olúwa, Ìwọ mọ̀ ohun gbogbo; Ìwọ mọ̀ pé mo fẹ́ Ọ." Jésù wí fún un pé, "Bọ́ àwọn àgùntàn Mi."
18. "Lótìítọ́, lótìítọ́ ni Mo wí fún ọ, Nígbà tí ìwọ wà ní èwe, ìwọ á máa di ara rẹ lámùrè, ìwọ á sì máa rìn lọ sí ibi tí o bá fẹ́: ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá dàgbà, ìwọ yóò na ọwọ́ rẹ jáde, ẹlòmíràn yóò sì dì ọ́ lámùrè, yóò sì gbé ọ lọ sí ibi tí o kò fẹ́."
19. Ó sọ èyí láti fihàn irú ikú tí òun yóò fi yin Ọlọ́run lógo. Nígbà tí Ó sì ti sọ èyí tán, Ó wí fún un pé, "Tẹ̀lé Mi."
-
​ÀLÀYÉ Ẹ̀KỌ́:
-
​Wọ́n máa ń sọ lọ́pọ̀ ìgbà pé àǹfààní tó bá ti lọ kò lè padà bọ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n, èyí lè jẹ́ òtítọ́ kìkì nígbà tí Ọlọ́run bá dákẹ́ lórí irú àǹfààní bẹ́ẹ̀. Ní kété tí Ọlọ́run bá ti bọ́ sí ọ̀rọ̀ náà, àǹfààní tó ti sọnù lè padà bọ̀.
​Ní nǹkan bí ọdún 1960, mo jẹ́ olùkọ́ eré-ìdárayá (games master) ní ilé-ìwé kan tí a ń pè ní Okeigbo/Ifetedo Grammar School. Ilé-ìwé náà gba ìpè láti kópa nínú ìdíje kan ní Àkúrẹ́, ọ̀kan lára olú-ìlú ìpínlẹ̀ ní apá Ìwọ̀-Oòrùn Nàìjíríà, mo sì bá olùkọ́ eré-ìdárayá ilé-ìwé tó gbà wá lálejò sọ̀rọ̀ nígbà ìdíje náà.
-
​Nígbà tó yá, mo gba ìwọlé sí Yunifásítì

11/04/2026

📖📖 *ÌWÉ Ọ̀RUN_ṢÍṢÍ, ÌTỌ́NI OJOJUMỌ FÚN IDAPỌ TIMỌTIMỌ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN.*
-
ỌJỌ́ ÀBÁMẸ́TA, ỌJỌ́ KỌKÀNLÁ, OSÙ KẸRIN, *ODÚN 2026*
-

**ÀKỌLÉ: YÍYÍ OHUN TÍ KÒ LÈ YÍ PADÀ PÀDÀ**
-
*AKỌSÓRÍ :*
-
> "ỌLỌRUN li àbo wa ati agbara, lọwọlọwọ iranlọwọ ni igba ipọnju.
– **Sáàmù 46:1**
-
*BÍBÉLÌ KÍKÀ: ESÌKÍẸ́LÌ 37:1-10*
**1.** Ọwọ́ Olúwa wà lára mi, Ó sì gbé mi jáde nínú Ẹ̀mí Olúwa, Ó sì sọ mi kalẹ̀ ní àárín àfonífojì náà tí ó kún fún egungun,
**2.** Ó sì mú mi kọjá lọ́dọ̀ wọn yíká: kìí kíyèsí i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni wọ́n wà nínú àfonífojì gbangba náà; sì kíyèsí i, wọ́n ti gbẹ gidigidi.
**3.** Ó sì wí fún mi pé, "Ọmọ ènìyàn, àwọn egungun wọ̀nyí ha lè yè?" Mo sì dáhùn pé, "Olúwa Ọlọ́run, Ìwọ mọ̀."
**4.** Ó tún wí fún mi pé, "Sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn egungun wọ̀nyí, kí o sì wí fún wọn pé, 'Ẹ̀yin egungun gbígbe, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.'
**5.** Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí sí àwọn egungun wọ̀nyí; 'Kíyèsí i, Èmi ó mú èémí wọ inú yín lọ, ẹ ó sì yè:'
**6.** 'Èmi ó sì fi iṣan lé yín, Èmi ó sì mú ẹran-ara wá sí ara yín, Èmi ó sì fi awọ bò yín, Èmi ó sì fi èémí sínú yín, ẹ ó sì yè; ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.'"
**7.** Bẹ́ẹ̀ ni mo sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti pàṣẹ fún mi: bí mo sì ti ń sọtẹ́lẹ̀, ariwo kan wà, sì kíyèsí i, ìmìtìtì kan, àwọn egungun náà sì kóra wọn jọ, egungun sí egungun rẹ̀.
**8.** Nígbà tí mo sì wò, kíyèsí i, iṣan àti ẹran-ara wá sí ara wọn, awọ sì bò wọ́n lókè: ṣùgbọ́n kò sí èémí nínú wọn.
**9.** Nígbà náà ni Ó wí fún mi pé, "Sọtẹ́lẹ̀ sí afẹ́fẹ́, sọtẹ́lẹ̀, ọmọ ènìyàn, kí o sì wí fún afẹ́fẹ́ pé, 'Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí; Wá láti afẹ́fẹ́ mẹ́rin, ìwọ èémí, kí o sì fẹ́ sí àwọn tí a pa wọ̀nyí, kí wọ́n lè yè.'"
**10.** Bẹ́ẹ̀ ni mo sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ó ti pàṣẹ fún mi, èémí sì wọ inú wọn lọ, wọ́n sì yè, wọ́n sì dìde dúró lórí ẹsẹ̀ wọn, ẹgbẹ́ ogun tí ó pọ̀ gidigidi.
-
*ÌRÒYÌN:*
-
Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ìdámọ̀. A ń pè É ní Olódùmárè (Jẹ́nẹ́sísì 17:1), èyí tó túmọ̀ sí pé Ó ní gbogbo ipá àti agbára, Ó sì lè ṣe ohun gbogbo. Nínú Jeremáyà 32:27, a pè É ní Ọlọ́run gbogbo ẹran-ara tí kò sí ohun tí ó ṣòro fú

11/04/2026

📖📖 *ÌWÉ Ọ̀RUN_ṢÍṢÍ, ÌTỌ́NI OJOJUMỌ FÚN IDAPỌ TIMỌTIMỌ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN.*
-
ỌJỌ́ ẸTÌ, ỌJỌ́ KẸWA, OSÙ KẸRIN, *ODÚN 2026*
-
ÀKÒRÍ:

*ÀWỌN ÀDÚRÁ FÚN ÌJỌ*
-
**AKỌSÓRÍ :*
> "Ẹ máa dúró nínú àdúrà, kí ẹ sì máa ṣọ́ra nínú rẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́;" –
*Kólósè 4:2**
>
**BÍBÉLÌ KÍKÀ: MÁTÍÙ 9:35-38**
**35.** Jésù sì rìn káàkiri gbogbo ìlú ńlá àti ìlú kéékèèké , Ó ń kọ́ni nínú sínágọ́gù wọn, Ó ń wàásù ìhìn-rere ìjọba náà, Ó sì ń wo gbogbo àìsàn àti gbogbo àrùn sàn láàrin àwọn ènìyàn.
-
*36.* Ṣùgbọ́n nígbà tí Ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, Ó kẹ́dùn wọn, nítorí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì, wọ́n sì fọ́nká káàkiri, bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.
-
*37.* Nígbà náà ni Ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ pé, "Ìkórè pọ̀ nítòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ kò tó nǹkan;"
-
*38.* "Nítorí náà, ẹ bẹ Olúwa ìkórè, kí Ó lè rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè Rẹ̀."
-
*ÀWỌN KÓKÓ ÀDÚRÁ:*
-
1. Olúwa, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ fún ìjọ Rẹ. O ṣeun fún ẹ̀bùn ara Rẹ àti àwùjọ àwọn onígbàgbọ́ olùfẹ́ Ọlọ́run.
-
2. Olúwa, jọ̀wọ́ fún gbogbo olórí nínú ìjọ Rẹ ní okun. Fún wọn ní ọgbọ́n, ìgboyà, àti ìpinnu láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti láti tọ́ agbo Rẹ.
-
3. Baba, jọ̀wọ́ fún ìjọ Rẹ lágbára láti ṣiṣẹ́ bí iyọ̀ ayé nítòótọ́, kí ẹnikẹ́ni tó bá wá sínú ìjọ lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìrírí dídùn nínú ayé wọn, ní orúkọ Jésù.
-
4. Baba, jọ̀wọ́ sọ ìjọ Rẹ di mímọ́. Ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ àpẹẹrẹ tòótọ́ ti ìjọ̀wọ́ mímọ́ Rẹ sí ayé, ní orúkọ Jésù.
-
5. Baba, jọ̀wọ́ lé gbogbo onírúurú òkùnkùn àti ibi kúrò nínú ìjọ Rẹ, ní orúkọ Jésù.
-
6. Baba, jọ̀wọ́ pèsè fún àìní ìjọ Rẹ. Pèsè gbogbo àìní wa gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ Rẹ nínú ògo, kí O sì fún wa lágbára láti ṣe iṣẹ́ Rẹ, ní orúkọ Jésù.
-
7. Baba, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ìfẹ́ Rẹ máa ṣàn tìfẹ́tìfẹ́ nínú ìjọ Rẹ. Ràn wá lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ ara wa tọkàntọkàn pẹ̀lú ọkàn mímọ́, ní orúkọ Jésù.
-
8. Baba, jọ̀wọ́ ràn àwọn tó ń gbé ayé àgàbàgebè nínú ìjọ Rẹ lọ́wọ́ láti ronúpìwàdà. Ràn wọn lọ́wọ́ láti jọ̀wọ́ ara wọn fún ọ̀rọ̀ Rẹ nítòótọ́, ní orúkọ Jésù.
-
9. Baba, jọ̀wọ́ fa gbogbo ẹ̀kọ́ èké àti àṣà tí kò ní Ọlọ́run nínú tu kúrò nínú ìjọ Rẹ. Jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn Rẹ

05/04/2026

📖📖 *ÌWÉ Ọ̀RUN_ṢÍṢÍ, ÌTỌ́NI OJOJUMỌ FÚN IDAPỌ TIMỌTIMỌ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN.*
-
ỌJỌ́ ÀÌKÚ, ỌJỌ́ KÀRÚN, OSÙ KẸRIN, *ODÚN 2026*
-
*ÀKÒRÍ*

​PÍN ÌRÒYÌN AYỌ̀ NÁÀ-II
​-
​ÀKỌ́SÓRÍ:
"Emi ti waasu ododo ninu ijọ nla: kiyesi i, emi kò pa ète mi mọ́, OLUWA, iwọ mọ̀." — Saamu 40:9
-
​BÍBÉLÌ KÍKÀ: 2 ÀWỌN ỌBA 7:3-16
(Ìtàn àwọn adẹtẹ̀ mẹ́rin tí wọ́n rí ìkógun àwọn ará SÍRÍÀ ti wọn si ké gbàjarè sita)
-
​ *ÀLÀYÉ Ẹ̀KỌ́:*
-
Bíbélì kíkà òní sọ fún wa nípa bí àwọn adẹtẹ̀ mẹ́rin ṣe gba gbogbo ìlú kan sílẹ̀ kúrò nínú ìṣòro ọrọ̀-ajé tó burú jáì.
Nígbà yẹn, ìyàn rorò ti wà ní Samaria fún ìgbà pípẹ́, nǹkan sì bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ìyá fi bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ ọmọ wọn (2 Àwọn Ọba 6:26-29). Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Èlíṣà, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pé nǹkan yóò yí padà sí rere ní ọjọ́ kejì. Láìmọ̀ nípa ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, àwọn adẹtẹ̀ mẹ́rin tó ń gbé lẹ́yìn ibodè ìlú pinnu láti gbé ìgbésẹ̀ akin láti lọ sí ibùdó àwọn ọ̀tá.
-
​Ìgbésẹ̀ wọn so èso nítorí Ọlọ́run ti mú kí àwọn ọmọ ogun ọ̀tá sá lọ nípa mímú kí wọ́n gbọ́ ariwo tó dà bíi ti ẹgbẹ́ ogun ńlá tó ń bọ̀ wá kọlù wọ́n.
Nígbà tí àwọn adẹtẹ̀ yìí wọ ibùdó ọ̀tá, wọ́n rí i pé gbogbo àwọn ọmọ ogun ti sá lọ, wọ́n sì fi oúnjẹ àti ẹrù wọn sílẹ̀. Ẹnu yà wọ́n, wọ́n jẹ, wọ́n mu, wọ́n sì kó fàdákà, wúrà, àti àwọn nǹkan iyebíye mìíràn. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, wọ́n dádúró, wọ́n sì bi ara wọn léèrè nípa ìmọ̀-tara-ẹni-nìkan wọn:
-
​"Nigbana ni nwọn wi fun ara wọn pe, Awa kò ṣe daradara: ọjọ́ oni jẹ́ ọjọ́ ihinrere, awa si dákẹ́: bi awa ba duro t**i di imọ́lẹ owúrọ̀, ibi kan yio bá wa: njẹ nisisiyi ẹ jẹ ki a lọ, ki a si sọ fun ile ọba." — (2 Àwọn Ọba 7:9)
-
​Àwọn adẹtẹ̀ náà mọ̀ pé ọjọ́ ìròyìn ayọ̀ ni, nítorí náà wọ́n kọ̀ láti pa ìròyìn náà mọ́ fún ara wọn nìkan. Wọ́n lọ ròyìn ohun tí wọ́n rí fún ilé ọba, báyìí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ìyípadà iṣẹ́-ìyanu nínú ọrọ̀-ajé ìlú náà ṣe nímùúṣẹ ní ọjọ́ kejì.
Bí o bá jẹ́ Kristẹni, o mọ̀ pé òní jẹ́ ọjọ́ ìròyìn ayọ̀. Jésù kú, Ó sì jíǹde láti mú wa wọ ọjọ́ tuntun. Jeremáyà 31:31 sọ fún wa nípa àwọn ọjọ́ tí Ọlọ́run yóò dá máj

Address

RCCG HOUSE OF LEVITES AREA HEADQUARTERS IBOROPA AKOKO ONDO PROVINCE 7
Ikare-Akoko

Telephone

+2349075527515

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when RCCG Yorùbá Manuals. posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Business

Send a message to RCCG Yorùbá Manuals.:

Shortcuts

Share