02/12/2023
ALAGEMO
Alagemo je ọkan nínú àwọn ẹranko tó wu ni jùlọ ní ìjọba ẹranko afàyàfà. Ó jẹ́ ẹranko tí wọn
mọ̀ gẹgẹ́ bí èyí tí ó ní agbára láti yí àwọ padà. Ìrísí rẹ̀ jẹ́ èyí tí ó lágbára. Ó jẹ́ ẹranko
aláwọ̀ tẹẹrẹ tí ó sì ní ojú dídán tí ó leè fi rí gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká a rẹ, níwájú, lẹyìn, tí kò
sì sí ohun kan tó pamọ́ fún irú ojú tí ó ní yìí. Alagemo jẹ́ kòkòrò ní pàtàkì ní ìṣèdá pẹlú ahón
gígùn tí ó jẹ́ ohun ìjà wọn láti mú ohunkóhun tí wọn fẹ́ jẹ. Ó jẹ́ ẹranko tí ó máa ń ní sùúrù
fún ohun ọdẹ wọn, kí wọn leè lo ahón ẹmọ wọn yìí láì tasé, tí ó fi jẹ́ pé, kò sí irú ohun tí ó bá ti
lẹ mọ́ ahọn yìí láti jẹ fún wọn tí ó tún le è jáde. Ẹranko yìí jé èyí tí ń mú ní rántí bí ayé ṣe wá ní
àìdọgba.
Àwọn nǹkan tí alagemo fi ń ṣe oúnjẹ ni àwọn kòkòrò bíi: ìrẹ̀ , Ẹlétẹ , eṣinsin, itù,, ekòló,
labalábá, alantakun àti bẹẹ bẹẹ lọ. Àmọ́ nnkan ti alagemo fi ń ṣe oúnjẹ yàtò síra wọn. Èyí dá
lórí tàbí níiṣe pẹlú irú ohun tí ó fẹ́ ìwọn rẹ̀ àti ibùgbé wọn.
A lè ka alagemo sí àwọn ẹranko ìgbẹ́ tí wọn máa ń gbé ní agbègbè ibi tí a gbé bí wọn bíi inú
igbó, aginjù, àti àwọn ìlú ẹdá abàmì mìíràn. A lè rí alagemo ni àwọn àgbègbè bíi Áfríkà,
Madagascar, Asia, àti díẹ̀ nínú apákan tí Gúsù ni Europe.
Ẹ jẹ́ kí á wo díẹ̀ nínú àbùdá tí alagemo ni
1. Ó jé ẹranko tí ó máa ń yí àwọ padà
2. Wọn ní àwọn ojú tí ó leè gbé pẹlu irọrun, èyí tí ó fún wọn ní ìwòye bíi otalelooodunrun
(360degree) Iríran láiyira padà
3. Àwọn ẹranko yìí ni ìrù kan tí ó jẹ́ pé nígbàkúùgbà tí wọn ba fẹ́ dimọ àwọn èka, irú yìí ni ó
máa ń ṣe iranlọwọ fún wọn láti lọ káàkiri àwọn igi àti ohun mìíràn èyí tí a lè fi kà wọn mọ́ ọga
nínú àwọn gungi-gungi
4. Alagemo ní àwọn ẹsẹ àmọja pẹlú ìka ẹsẹ tí ó lẹ papọ̀ , èyí tí ó fún wọn ní ààyè láti di àwọn
èka igi mú àti ojú ilẹ̀ mìíràn pẹlú ààbò tí ó péye fún wọn
5. Alagemo ní ahọn gígùn pẹlu itọ ẹmọ èyí tí wón máa ń lò láti mú àwọn kòkòrò kí kòkòrò tí wọn
fẹ́ pa jẹ
6. Wọn ní àbùdá yíyọ rìn, èyí tí kò ní fún àwọn ọdẹ ni àǹfààní láti rí wọn tàbí funra láti sá lọ
Èyí ni díẹ̀ tí a lè sọ nípa alagemo. Kò tán síbẹ̀ o, nítorí ó kù! ó kù! báyìí nibon ń ro. Ẹ tún
pàdé wa ní ìkànnì yìí lórí ètò ògbójú ọdẹ lọsẹ tó ń bọ. A gbáà ládúra pé ojú tẹ fi ń wò wá ò ní fọ,
bẹẹ̀ letí tẹ fi ń gbọ́ wa ò ní di. A ó máa lọ a sì máa de, tí a bá sì ń de, ẹyin naa là ó máa dé bá
láṣẹ Eledumare. Ire ó.
Ogundulu Beatrice Temitope
Bikear TV