28/10/2022
D.O. FAGUNWA: ÒǸKỌ̀WẸ́ YORÙBÁ TÍ ÀWỌN ÈNÌYÀN KA ÌWÉE RẸ̀ JÙLỌ LÁÀÁRÍN ÀWỌN AKẸGBẸ́ Ẹ̀.
Daniel Olorunfemi Fagunwa MBE (1903-1963), tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí D.O. Fagunwa, jẹ́ òǹkọ̀wé ìwé ìtàn Yorùbá àkọ́kọ́. A bíi sí ìlú Òkè-Igbó ní Ìpínlẹ̀ Òǹdó ní ọdún 1903.
Fagunwa lọ sí ilé ìwé St Luke ní Òkè-Igbó, àti St Andrews College ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, kí wọ́n tó di Olùkọ́ni.
Ní ọdún 1938, Fagunwa kọ ìwé Ògbójú Ọdẹ nínú igbó Irúnmọlẹ̀, ìwé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbà wípé ó jẹ́ ìwé ìtàn àkọ́kọ́ ní èdèe Yorùbá. Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka sì ṣe ògbífọ̀ ìwé yìí sí èdèe Òyìnbó ní ọdún 1968, tí ó sì pèé ní "THE FOREST OF A THOUSAND DEMONS"
Fagunwa lẹ́yìn ò-rẹyìn kọ àwọn ìwé mìíràn bíi : Igbó Olódùmarè (1949), Ìrèké Òníbùdó (1949), Ìrìnkèríndò nínú igbó Elégbèje (1954) àti Àdìtú Olódùmarè (1961). Àwọn ìwé Fagunwa jẹ́ èyítí ó sọ nípa àṣà, ìṣe, òwe, òrìṣà, àǹjọ̀ọ̀nú, ẹranko, ewé, egbò, èsìn, ìkónilẹ́rú, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Fagunwa gba àmì ẹ̀yẹ ti Margaret Wong ní ọdún 1955, àti àmì ẹ̀yẹ Member of the British Empire MBE ní ọdún 1959.
Alàgbà Fagunwa kú sí inú odò Wuya ní Bida, Ìpínlẹ̀ Niger ní ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù Ọpẹ́, ọdún 1963. Ilẹ̀ ṣàdédé ri mọ́ wọn lésẹ̀ létí odò yí ni. Fagunwa jà raburabu láti wẹ̀ jáde sókè eèpẹ̀ ṣùgbọ́n tí aṣọ kò bá omọ́yẹ mọ́. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta; wọ́n rí òkú bàbá yìí. Wọ́n jẹ́ ẹni ọgọ́ta ọdún ńìgbátí wọ́n dágbére fáyé pé ó dìgbà ó ṣe.
Àwọn ilé ìwé tí wọ́n fi sọrí akọni yìí ni Fagunwa Memorial High School, àti Fagunwa Grammar School ní Òkè Igbó ní Ìpínlẹ̀ Òǹdó, bákannáà Ilé Ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì Èkó ní Àkọkà forúkọ Fagunwa pe ọ̀kan nínú ilégbèé (hostel) àwọn akẹ́kọ̀ọ́, Fagunwa Hall of Residence.
Onírèsé D.O. Fagunwa kò fíngbá mọ́ lóòótọ́, ṣùgbọ́n èyí tí wọ́n ti fín sílẹ̀ kò leè parun láí. Wọ́n ti kú, ṣùgbọ́n àwọn iṣẹ́ wọn ń fọhùn síbẹ̀.
Yorùbá Ọládàpò Olúdáre Peace'bàbá