Ohun tó yẹ kómo Tv

Ohun tó yẹ kómo Tv I'm Paul Adewumi a man that like to let his people know more about this world.

I want my people to know who God his before they race there voice to pray to him for anything.

24/12/2024
11/09/2024

ORO ISO SAJU

Ara nínú Oluwa, a o ri wípé, lórí ọrọ ìgbéyàwó l'ode t'onì, ló dàbí ẹni wipe, ìdá marundinladòrun, nínú ìdá ọgọrùn 85/100 ìdílé, ni wọn n gbé, gẹgẹ bi olongbo àti èkúté ilé.

Ìdí tí mo fi sọ bẹẹ, ni wípé, ọpọ ọkọ àti ìyàwó, ló n gbé pẹlú ọtẹ gbígbọná, ìjà àti aṣọ, to dàpọ mọ wàhálà, ifooro àti idanilaamu tó lágbára, igbọwọ l'enu àti lé iṣẹ ẹni, ìbànújẹ àti pipọn ni lójú, bẹẹ tọkọtaya na ni a n pe wọn, ti wọn si n bi awọn ọmọ wọn sinú rudurudu, pẹlú aisi ifọkanbalẹ, àti ogun gbígbọná, ni àárin awọn mejeeji.

Ni ikorira yi, ni ọpọ ti n gbé ìgbé ayé ìgbéyàwó tiẹ, gẹgẹ bi ẹni tó wà nínú ọgbà ẹwọn.
Nígbàtí, ìgbéyàwó ti ọpọlọpọ si dàbí ẹni tó wà l'oko ẹru, tàbí l'oko ìsìnrú, ti inú ilé ọpọ si n gb'ona bi ilé iṣẹ burẹdi.

Ni iru ikorira yi ni ọpọ ọkọ ti di òrìsà àkuńlẹbọ fun awọn ìyàwó wọn, ti ọpọlọpọ obìnrin na si di ẹrù jẹjẹ fun awọn ọkọ wọn.

Ikorita yi ni ilé ọkọ ti yípadà, to si di ibùdó ogun fún ọpọlọpọ obìnrin. Nígbàtí ọpọ si di ẹdun arinlẹ pátápátá.

Ọpọ lo si di ẹni ẹyin àti ẹni ofo. Ọpọ ni ikorita yi si sọ di àgàn alẹ, ti ko ni aṣọ ìbora Kan-kan lára mọ, nígbàtí aṣọ ìbora ọpọlọpọ si ti di fifaya, to si di àkísà lasan-lasan.

Ohun ti Ẹmi n sọ níbí na ni pe, bi ọpọ ti se abiyamọ to nínú ayé, àsìgbé ẹsẹ ti wọn ti gbé sẹyìn, ti wọn ko si funra, asiyan yi, lo wa n pa awọn ọmọ rẹ ni ọkọọkan, ti awọn to ku láàyè na ko si ni láárí mọ, wọn ko se fi yangan.

Ni ikorita yi ni ọpọlọpọ ti di aláìsàn, ti ọpọ si di alaabọ ará. Ikorita yi lo ma sọ ọpọlọpọ di idakuda, ti ọpọ si di ẹlẹmi Esu.

Ikorita yi na lo ma sọ ọpọ di isansa àti alarinkiri, nígbàtí ọpọ si di ọlọmọ márùn, Bàbá márùn, ti ọpọ si padà di dálé mosu, àti ìyá n dagbe, níbi ti onírúurú ẹgbin àti àbuku pẹlú iwọsi ti ntà leè.

Mo ma tun gbàá ni ádùrá wípé, Oluwa Ọlọrun alaanu yio gbè ọ níjà, Oluwa yoo gba ìjà rẹ jà, wa bọ kúrò nínú ọfin ìgbéyàwó, èyí to bọ si, tàbí to fẹ bọ si, amin.

Ẹyin Màmá Màmá àti ẹyin Anti mi nínú Oluwa, òwe Yorùbá kan sọ wípé, àìmọ ki pa ọmọ ọlọmọ.
Ṣugbọn ni ti ọrọ ìgbéyàwó, ko ma ri bẹẹ, àìmọ a ma pa'ni, ko da, o tún lágbára láti fi'ni sínú ide, àti sínú túbú ìgbéyàwó dáadáa.

Iwe yi, ti Ẹmi Mimọ pe àkọlé rẹ ni ỌFIN ÌGBÉYÀWÓ, TÀBÍ OHUN TO LE MU NI JIN SÍNÚ ỌFIN ÌGBÉYÀWÓ,
A o ri wípé, gbólóhùn na báni l'ẹru púpọ, mo si gbagbọ wípé, ko si obìnrin na ti yóò fẹ ki oun jìn sínú ọfin ìgbéyàwó, bẹni, mo n'igbagbọ bákan na, wípé, ko si obìnrin na ti yóò fẹ ki irú ọmọ oun jìn sínú ọfin ìgbéyàwó.

Nitori pe, ọpọ wa ni a mọ wípé, ibi idibajẹ ni a npe ni ibi ọfin, bẹ la mọ wípé, ààyè ti ko dára ni inú ọfin jẹ, inú idamu ni inú ọfin, ki se ibi ti ènìyàn le fi ara balẹ ma gbé.

Inú ọfin ìgbéyàwó yi ni ọpọ si wa báyìí, ààyè ti ki se ibi ifọkanbalẹ, ti ọpọ abilékọ si wa ní irú ipò bẹẹ l'oni, irú awọn ti a n fi ojú ara wa ri ni àyíká wa, àti ni awujọ wa.

Ikorita ti ọpọ obìnrin ti l'ọkọ nitotọ, ti se adé orí obìnrin, ṣugbọn ti ko ri igbadun àti ifọkanbalẹ ọkọ na, awọn ti ìgbéyàwó wọn ko ni adùn, tàbí ti adùn ìgbéyàwó tiwọn ti yípadà di ikoro.

AYA TO ṢIṢẸ SIN ỌKỌ, ṢUGBỌN TI KO RI ÈRÈ ỌKỌ NA JẸ.

Ikorita ti ọpọ obìnrin abilékọ ti ma n seré nita, ti oun na a ma ba awọn ẹlẹgbẹ rẹ s'ere, ti ẹrín a si ma bọ l'ẹnu rẹ, ṣugbọn, ti ìbànújẹ èyí to ju ti kikorò ewúro lọ wa ni inú rẹ, a seré rérìn ni'ta, to ba de inú ilé rẹ, ti kii lee daraya mọ, nítorí ìbànújẹ ti ọkọ rẹ ma fun un, nitori pe o ti jìn sínú ọfin ìgbéyàwó.

Iwọ obìnrin to n ka ìwé yi, ìmọràn mi si ọ ni wípé, jọwọ dáwọ rẹ dúró na nínú arokan, fi ara rẹ balẹ diẹ na, fún iji èyí to njà ìgbéyàwó rẹ, ma se kánjú gbé ìgbésẹ, èyí ti o fẹ gbé yi, ma iti ko ẹrú rẹ jáde bẹ, ma iti fi ìwé ikọsilẹ le ọkọ rẹ lọwọ.

Èyí ni ki o kọkọ se, fi ara rẹ balẹ diẹ sii, nítorí pe ìgbésẹ èyí to fẹ gbé yi, tun le mu ki ọfin rẹ ma jìn sii, ma subu-lebu, gbìyànjú fi ara balẹ ka ìwé kekere yi na, ki o si tẹle awọn itọni gbogbo to ba fun ọ, gbìyànjú, fun Ẹmi Mimọ láàyè, ko dasi ọrọ ìgbéyàwó rẹ.
Jọwọ ma se kọ ìbáwí Ọlọrun yi, lẹyìn ti o ba ti se àṣàrò yi tan, tọ ojúlówó ìránṣẹ Ọlọrun lọ fun itọni sii, lori ohun ti ìwé kékeré yi ba kọ ọ, pẹlú ìgbàgbọ, mọ wípé, ọrọ rẹ a di ayọ, ọkàn rẹ yóò si balẹ, wa si yin Ọlọrun l'ogo, ìmọràn Ọlọrun rẹ ni ki o tẹle, yio si gbà ọ, yio si dára fun ọ, àti fún ìdílé rẹ àmín.

08/07/2024

Ọrẹẹ, ma gbìyànjú a ti ba wọn lọwọ nínú ìkà ṣiṣe.

Bi o ba wa n bá wọn ṣe ìkà, iwọ na ma retí ẸSAN.

22/05/2024

Bí o ba gbagbọ, tiẹ ni. Bí o ba sì tún jẹ alaigbagbọ, tiẹ ni.
Ohun tó dájú ni wípé, Jesu kristi n padà bọ, kódà o dé tán, lati wá ko awọn ti wọn gbàá gbọ, ti wọn sì n se gbogbo ifẹ rẹ, lọ sí ibi ìsinmi ayọ ayérayé, PÁRÁDÍSÈ ILÉ OLOGO.

Address

Ibadan

Telephone

+2348066227199

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Ohun tó yẹ kómo Tv posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Business

Send a message to Ohun tó yẹ kómo Tv:

Share