12/07/2024
ÌDÚPẸ́ PÀTÀKÌ GÉGÉ BÍI OMO TÍ Ó MO OORE
Oríì mí wú, Ìnú mì dùn fún bí ese pónmile fún ayeye ojó ìbí mi
E seun, modúpé lówóo àwon tí wón fi àtèjísé ránsé
Modúpé lówóo àwon tí wón pèmí lórí ago
Modúpé lówóo àwon tí wón kòmílónà kími kú oríire
Taa ni mo jẹ́ láwùjọ àwọn ènìyàn?
Ẹ̀dá wo ni mo jẹ́ nínú àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀?
Nínú iṣẹ́ agbóhun sí aféfé, mo kéré
Nínú ìmọ̀, Jòjòló ni mí, n kò lérò púpọ̀ láwùjẹ̀
Mo wá di ẹni ayé ń kí kúu Oríire
Mo dèèyàn tí ẹ̀yin àgbà ìpèdè ń rọ̀ lọ́kàn
Òótọ́ lọ̀rọ̀ àgbà pé, èèyàn laso èèyan
Mo dúpẹ́, mo dú pẹ̀pẹ́ òkun
Ire la ó fi san fún ra wa
Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ pè mí láago, Omo Fálétí n dúpẹ́
Gbogbo èyin olólùfé mi, Adéníyì ń bẹ lórí ìdọ̀bálẹ̀
Mo ti mọ̀ báyìí pé mo ní èjìká tí kò mú aṣọ yẹ̀ lọ́rùn
Ire lẹ ó fi gbà á, ẹ kò ní papòdà
Ojú ti ń ro mí, mo fẹ́ wúre
Ẹ bá mi tẹ́wọ́ àdúrà, Adéníyì fẹ́ sàdúrà
Ikú àìtọ́jọ́ kò níí pa ẹnìkan- kan nínú wa
Àìsàn kò níi gbé wa dè, ẹ ṣe amí wìtìwìtì
Kò níi báàjé fún n yín
E ò ní subú dàánù
Ire lá ma bá ara wa se o.
Bí ikú di tọ́rọ́-fọ́n-kálé kò níí pa yín
Bí àìsàn ogbó bá di nǹkan gbajúmò, kò níí yà sọ́dọ̀ rẹ
A ó rí ara wa pẹ́, a kò níí rí ogun ìdárò
ADÉNÍYÌ N KÍ YÍN PÉ ESEUN O