17/01/2026
GÓMÌNÀ SANWOOLU PÀṢẸ KKÍ ÌWÁDÌÍ Ó WÁYÉ LÓRÍ IKÚ ÀWỌN ỌMỌ ÌBEJÌ TÍ WỌ́N KÚ LẸ́YÌN ABẸ́RẸ́ ÀJẸSÁRA.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó; Babajide Sanwoolu ti pàṣẹ kí ìwádìí ìjìnlẹ̀ ó wáyé lórí ikú àwọn ọmọ ìbejì tí wọ́n kú lẹ́yìn wákàtí mẹ́rìnlélógún tí wọ́n gba abẹ́rẹ́ àjẹsára.
Gómìnà sọ èyí lẹ́yìn tí bàbá àwọn ọmọ náà fi ẹ̀sùn kan ilé ìwòsàn ìjọba alábọ́dé kan tó wà ní Èkó pé abẹ́rẹ́ àjẹsára wọn ló pa àwọn ọmọ rẹ̀ ìbejì ọkùnrin méjì.
Gómìnà bá Samuel Alozie; bàbá àwọn ọmọ náà kẹ́dùn, ó ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú àwọn ọmọ méjì náà. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé wọ́n ti fún ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ní abẹ́rẹ́ àjẹsára tí wọ́n fún àwọn ìbejì náà ṣáájú wọn àti lẹ́yìn tí wọ́n fún wọn tí kò sì sí èyí tó gbòdì lára rẹ̀.
Èsì àyẹ̀wò òkú àwọn ọmọ náà yóò jáde síta lọ́gán tí àyẹ̀wò náà bá parí – ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó.