14/11/2025
ADETUTU EPISODE 33
(THE FINAL EPISODE)
... Ọjọ ti Gbuyi gba esi ayẹwo yii O sáré lọ bá Dókítà agba kan ti o mọ daada, Dokita naa sí ṣalaye fún wipe: Ibimọ papọ awọn mejeeji lẹ gidigan. Iroyin yi ba Gbuyi ninu jẹ, O sunkun níwájú Dókítà.
O sọ fún Dọkítà wipe, O wù oun ki oun fẹ iyawo oun pada, wipe eeyan daada ni, O sí ní suru pẹlu pupọ, oun nifẹ rẹ gidigan! Dókítà ni, ti iyawo rẹ bá gba, ki wọn gbiyanju awọn ọna omiran ti wọn le fi ni Ọmọ laye. Lẹyìn gbogbo igbiyanju wipe ki awọn mejeeji pada fẹra wọn, Kikẹ ni ki o yanda oun nitori oun ti ayẹwo naa sọ, pẹlu omije ni awọn mejeeji fi yanda ara wọn ni iwaju awọn Obi wọn mejeeji....
..Leyin oṣu mẹfa ti Ọga Kikẹ ti n' ba a sọrọ fifẹ, Kikẹ sọ fún Ẹgbọn rẹ ki o jẹ ki Ọrẹ rẹ, ti n'ṣe Ọga oun,naa lọ fún Ayẹwo iru èyí ti gbuyi ṣe, Ọga rẹ gba, wọn sì ṣe ayẹwo naa, nigba ti esi jade, Ẹjẹ awọn mejeeji ṣe rẹgi!
Nigba ti gbogbo ebi gbọ sí, won bere lọwọ Kikẹ oun to fẹ, O sí ní òun yíò fẹ Ọga oun, sugbon o, o wù oun ki oun kuro ni Orilẹ Ede Naijiria fún ìgbà díẹ lẹyìn igbeyawo.
Bayi ni Igbeyawo Kikẹ ati Ọlakanmi, Ọgá rẹ ṣe wáyé ni Oṣù keji Ọdún. Nigba to di Oṣu kẹta Kikẹ ma loyun oooo! Idunnu ni eleyi jẹ fún gbogbo idile Kikẹ! Ọga Kikẹ mu Kikẹ lọ sí Dubai fún odidi Ọdún meji gẹgẹ bí Kikẹ ṣe fẹ. Nigba ti K**e bímọ, Iya kikẹ wọ Ọkọ Òfurufú fún ìgbà àkọkọ lọ sí Dubai lati lọ bá Kikẹ tọju Ọmọ.
Lẹyìn Ọdun meji ti Kikẹ lo ni Ilu Dubai, Kikẹ , pada sí Ilu Eko ni ile iṣẹ tuntun ti Ọkọ rẹ ṣẹṣẹ da silẹ. Wọn sì n' ba igbesi Ayé wọn lọ.
Ni Aarọ Ọjọ Sátidé kan ni Kikẹ nka IROYIN ILẸ ÒKÈRÈ kan lórí foonu rẹ, Wọn gbe aworan Ọkunrin kan sibẹ ti o fi mọto tẹ iyawo rẹ fọ yanyan! wọn kọ sibe wipe arakunrin yii fi mọto tẹ iyawo rẹ pa ni iwaju ile ni ìlú UK,bi Kikẹ ṣe ka iroyin naa síwájú, iroyin naa sọ wipe, Arakunrin naa ti gba Gbogbo nkan ini iyawo rẹ,to sì ti ba obinrin omiran lọ, iroyin naa sọ wipe, ni" ṣeni iyawo rẹ binu lọ bá Ọkọ rẹ ni ile Obinrin Omiran ti Ọkọ rẹ ko lọ bá, lati lọ dún kokó mọ wipe oun yíò fi ẹjọ rẹ sun awon Ọlọpa,oun a sì rí wipe wọn deport rẹ pada sí Naijiria, iroyin naa sọ wípé bi Ọkọ ṣe gbọ gbólóhùn yìí, ọ bọ sinu Ọkọ̀, O sí fi Ọkọ̀ náà rin ní Ori iyawo rẹ ti ifun ati Edọ rẹ fi jáde! Nigba ti awọn Ọlọpa dé,ni Ọkọ ba bẹrẹ sí ni ṣe bi Alaganna.
Bayi ni awọn Ọlọpa ṣe mu Ọkọ lo sí Ẹwọn ti wọn sì kó,Oku iyawo to fọ sílẹ lọ sin. Bi Kikẹ ṣe kan Iroyin yii tan, O pariwo! Yeee! Ọlọrun ma jẹ kí a ri iru eleyi ooo! Ọkọ Kikẹ sáré sita, nigba to gbọ Ariwo gbólóhùn tí Kikẹ sọ, O ni, dear kilo ṣẹlẹ, mo gbọ ariwo ẹ, Kikẹ salaye iroyin ilé Oke're ti O ka,
Iroyin naa ba Ọkọ k**e ninu jẹ, O gba foonu Kikẹ O sí ká iroyin naa síwájú sí, laarin kan, Ọkọ Kikẹlọmọ ni, OMG, ADETUTU ni orúkọ arabinrin naa ṣa, Olorukọ ọrẹ ẹ to sọrọ ẹ fún mi.
Kikẹ gba foonu naa pada, O ka iroyin naa siwaju,lo ba ri wipe, Adetutu Gorimapa ọrẹ oun gangangan ni ẹni náà! O pariwo yeeh! Adetutu ni ooo! Haa! Iku gbóná re óò! Haa! ADETUTU ! O sí fi wàdùwàdù baye ara re jẹ! Oun to ṣe fún mi, Mo dariji ẹ óò! Nítorí, Ibi ire lo fi timi sí! Mo dariji ẹ! Kikẹlọmọ bu sẹkun, Ọkọ rẹ sí fa mọra.
NI LỌKỌJA NIBI TI GHUYI TEDO SI..
Ni Lọkọja nibi Iṣe GBUYI, Awọn ọrẹ rẹ n'ba dupẹ wipe o pada ri Obinrin to loyun fún.Obinrin meji Otooto ni wọn ti kuro lọdọ rẹ lẹyìn tí Ọrọ Kikẹ ṣẹlẹ, Wọn kúrò nítorí airi Oyun ni.Sugbon,leyin Odun mẹje ti K**e ti bi Ọmọ mẹta,ni Ile Ọkọ rẹ, ni Gbuyiii ṣẹṣẹ pade , Obìnrin ẹlẹẹkẹrin to ṣẹṣẹ rí loyun ni fún, Obinrin alakọkọ ni K**ei, Elekeji ni ADETUTU, Ẹlẹẹkẹta to fe lẹyìn Ìgbéyàwó Kikẹ ni Mosun, Ẹlẹkẹrin to wa ri Oyin ni fún ni Ṣọlape.
Ìgbésíayé Kikẹlọmọ dun gidigidi gan ju ti atẹyinwa lọ.
Gbuyi dupẹ lọwọ Ọba Òkè wipe, Aye òun
O pada bajẹ tan yanyan ,O sí dupẹ lọwọ ANGELI AYE RẸ TI N' ṢE ỌKỌ KIKẸ NI ỌJỌ TONI.
ADETUTU KO ERE IṢẸ ỌWỌ RẸ PẸLU IKU GBIGBONA.
ITAN PARI....
SUPPORT THIS PAGE WITH LIKE, COMMENT, SHARE & FOLLOW.
Tell friends and family about this page where we tell amazing stories. Thank you for your support.
Ẹ Seun pupọ.
Watch out for another interesting story.
ADUTUTU IS ORIGINALLY WRITTEN BY YORÙBÁDÙNTÒ - BACKUP GANGAN
LIKE, FOLLOW, SHARE & COMMENT
゚viralシfypシ゚ ゚viralシ lia