
21/08/2023
Ó burú pùpọ́ pé ilé wiwó ti wá gba òde kan ní orílẹ̀-èdè Nàíjírià. Ó ti dàbi pé ojojúmọ́ ni á má n gbọ́ ìròyìn búburú náa pé ilé wó, yalà pé ó wo pa àwon olùkọ́lé tàbí pa àwọn ènìyàn tín gbé inú rẹ. Ìṣẹ̀lẹ̀ aburú yìì ti mú ẹ̀mí òpò ènìyàn lọ, bèeni òpò ènìyàn sì ti padanú dúkìa rẹ̀.
Nínu àkọsílẹ̀ yí, a ó ma sọ̀ ìdí tí ilé ṣé nwó àti bí a se lè dẹ́kun rẹ̀ ní orílẹ̀ ede wa.
1. Kíkọ́ ilé ní ònà tí kò dára: Èyí túmọ̀ sí wípé wọn kò tẹ̀lé ìlànà tí a lá sìlẹ́ nínù ìwé akọsilẹ̀ ìmọ̀-ẹ̀rọ ìkọ́lé.
2. Lílo ohun ìkọle ayédèru: gbígba ọ̀nà ẹ̀bùrú láti dín iye owó tí a fi kọ́lé má n fa ti àwọn èyàn sé nlo ohun èlo ayédèrú. Tí a bá lo ohun ìkọ́lé tí kò kún ojú òṣùwọ̀n, ile ò lè ní okun láti ṣé iṣẹ́ tío jẹ kó ṣẹ́.
3. Àwọn àjálù àdáyébá: àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bi ọ̀gbàra omíyalé, ìjì líle, ilẹ̀ ríru, àti bẹẹbẹẹ lọ. A lè dẹ́kun sí kí ilé wó nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ yíi tí a ba gbè iṣẹ ikọ̀le wa fun onìmọ̀-ẹ̀rọ tíó yege.
4. Àwọn ilé ti o tí gbo: awọn ile bajẹ akoko aṣe re kọja nitori àlòbàjẹ́, idípẹtà, tabi itọju aipe. Eyi fa irẹ̀wẹ̀sì sí igbékalẹ̀ wọn, ó sì mú ewu ilé wíwó pọ̀ si.
5. Ikójọpọ̀ ẹrù tí o pọjù: tí ilé kan bá wà lábẹ ẹrù tí o pọ̀ ju agbára tí a pinnu rẹ̀ lọ, bi àpẹẹrẹ; sísọ ilé gbígbé di ilé ìjọ́sìn, fìfi àwọn ohun èlò tí ó wúwo kún ilé, ó lè já sí ìkùnà ìgbékalẹ̀ àti wíwókalẹ.
6. Àwọn ìjàmbá ákòkò ìkọ̀lé tàbí átúnṣe ilé: àwọn ìjàmbá lákòkò ìkọ́lé tàbí àwọn iṣẹ́ àtúnṣe, gẹ́gẹ́bi ìṣubú Kírénì, àwọn ìkùnà iyẹfun, tàbí wíwó ilé ní ọ̀nà tí kò tọ́, le jà sí ìparun tí àwọn ilé tàbí àwọn apá kan ti ilé naà.
Láti rii ìdánilójú ààbò àti ìdálẹ́kùn ilé wíwó, ó ṣe pàtàkì láti lo àwọn alámọ̀jà onímọ̀-ẹ̀rọ ìlú, àwọn ìlànà ìkọ́lé tó dára, àti láti ṣe ìtọ́jú déédé, ṣíṣe àwọn àyẹ̀wò láti ṣe ìdánimọ̀ ibi tó nílò ìtọ́jú lára ilé.
Nípa gbígbé áwọn ìṣọ́ra ààbó wọ̀nyí, a lè ṣiṣẹ́ sí ìdínkù ìṣẹ̀lẹ̀ ti ilé wìwó ní orílẹ́-èdè wa.