17/07/2025
Ẹniìtàn-Awẹ́ kìíní
Tólání wá ní ẹ̀yín àgbàlá ilé rẹ̀, ó ti ronú gbàgbé ara rẹ̀ sí orí àpòtí tí ó jókòó lé. Ó ń dá rónú " orí Ọ̀kẹ́rẹ́ koko láwo, bàa wí fún ọmọ ẹni a gbọ́. Ìbáwí níí síwájú ìparun. Hmm… a kò kúkú ní wí fún ọmọdé pé kí ó má dẹ́tẹ́ níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti le dá igbó gbé" irú ayé ti àìgbọràn máa ń mú ní gbé kò rọrùn, ayé alààyè ni èèyàn máa ń gbé ní ọ̀pọ́ ìgbà, àfi bí ẹni sìn Wọ́n wáyé. Bí ènìyàn kò bá sì gbé irú ìgbé ayé baun, a jẹ pé ìgbẹ́ kiun yóò di kòlọmọ́ sétí àwo gbẹ̀gìrì ayé ẹni. Àbí irú ayé wo wàá lèyìí, láti ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n kí ènìyàn sì wá máa ko àjọ́ àìgbọràn, kí ènìyàn sì máa wò egbò tí àìgbọ̀ràn fí sí ojú orúkún ẹni. Èyí gan-an kọjá egbò àdákòjiná. ".... Ó bú sẹkún gbaragada.
Àròkàn tí Tólání ń rò yìí kò jẹ́ kómọ̀ pé ẹnìkan dúró lẹ́yìn òun. Ẹniìtàn dúró tiiri sẹ́yìn Tólání, ó ń wòó tìkàtẹ́gbin, ó pòse sàràsà. Tólání sì wà lórí Àròkàn rẹ̀, ṣe bí ẹni tó bá wo ojú ìyàwó ní yóò mọ̀ bóyá ìyàwó ń sunkún. Tólání kò mọ́ bóyá ẹnìkankan wà lẹ́yìn òun, kò tilẹ̀ mọ̀ bóyá ẹnìkan pòsé sàràsà. Ó tún ronú síta pé " báwo wá ni mo ṣe lè rí májélé náà, ọ̀nà wo ni mo le gbà?"
Àyà ẹniìtàn já pàtì bí rọ́bà fáànù ọkọ̀ tó já ṣùgbọ́n ìkórìíra àti ọgbẹ́ ọkàn tí fọ́ ojú àánú rẹ̀. Ó fọhùn, Ó ní "ẹ fẹ́ gbé májèlé jẹ́ àbí kíni mo gbọ́……… Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá Tólání lójijì nítorí kò mọ̀ pé ẹnìkankan wà ní ẹ̀yìn òun. Kí ẹniìtàn tó sọ̀rọ̀ jálẹ̀ ni Tólání ti ṣubú lulẹ̀ yakata tí ó sì dákú lọ gbọnrangandan. Ẹniìtàn ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìbínú," síọ̀, ẹ jẹ́ dìdè nílẹ̀, bí ẹ bá fẹ́ kú, kò sí ẹni tó ní kí ẹ mọ́ gbọ̀runlọ, àwọn tí kò tó yín tí kú, àwọn tó jùyín tí dẹni ànà, pàápàá jùlọ, àwọn tí Wọ́n gbé ayé tó ní ìtumọ̀, tí wọn kò fí ìgbésí ayé wọn ní ọmọ wọn lára, àwọn lamọ̀ pé wọn wáyé, wọn gbé ayé, wọn sì kú ikú tó ní ìtumọ̀, ẹ̀yìn wọn dára torí ilé ọkọ orí wọn ni Wọ́n sìn Wọ́n sí, wọn kò dálémosú sí ilé bàbá wọn kí Wọ́n má tilẹ̀ gbé ilé ọkọ wọn ní òwúrọ̀ kan di alẹ́ rí bíi ti yín yìí. Ẹ jẹ́ dìde, àbí ẹ kò ní dìde. Ẹ sọ ohun tí èmi fẹ́ mọ̀ fún mi ná kí ẹ tó gbọ̀runlọ, ẹ má sọ mí ṣókùnkùn ayérayé. Ẹ jẹ́ kí ayé tèmi náà kóní ojútùú. Àbàwọ́n burúkú ni ìyàn ogún ọdún tí ẹ gbé pamọ́ tí dá sí ayé mi. Gbogbo ọwọ́ mi ni ó ti bó fáláfàla torí bíi ó ṣe gbóná tó. Àná yín korò bíi jogbo, ìgbésí ayé yín dà bí ìsápá. Sebí àwọn àgbà tilẹ̀ sọ pé, ìka tí ó bá sẹ̀ ni ọba máa ń gé? Èwo ni tèmi nínú gbogbo ọ̀ràn yìí? Àbí kí ẹ kúkú má wàá bí mi gan án kò sàn jú hílàhílo tí ẹ kò bá mi yìí lọ? Elédùmarè, dàkún wáá gbà mí ó "
Ẹni ìtàn ríi pé Tólání kò mira rárá, ó sún mọ́ Tólání, ó fàá ní ọwọ́ sókè níbi tí ó ṣubú sí yakata, ọwọ́ Tolani yọ̀ bọ́ pọ́rọ́ ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹniìtàn pariwo " háà, mo gbé! Èèmọ̀, èmi kọ́ ni mo pá Wọ́n ó, àbí ṣe Wọ́n tí jẹ májélé tí Wọ́n dárúkọ lẹ́ẹ̀kan ni?"
Ẹ kú ojúlọ́nà