16/08/2025
Bómodé Láso Bí Àgbà
Omodé Ìwòyí e kú oge síse
Ipéèrè ìwòyí e kú àrà dídá
Èwo lojú ò rí rí lóhun e n se?
Èwo letí ò gbó rí lóhun e n fò?
Ilé yín làfojúdi pèkun sí.
Ilé yín nìrera pabùdó tì.
Èyin gbàgbé ni-ìn,
Pé arúgbó soge rí,
Pé àkísà lògbà rí,
Pé ìgbágbó sì ti sèsó rí
Kí le gbé té è n gbin?
Kí le se ténìkan ò se rí?