21/08/2023
ÀYÁJỌ́ ỌJỌ́ ÌSẸ̀ṢE, ṢÈYÍ MÁKINDÉ, ÌRÁNṢẸ́ ÌSỌKAN ÀTI ÀLÀÁFÍÀ
Ifá ni:
Ká mú inú ko inú ká lè baà ní ọlá
Ká mú ìwà ko ìwà ká lè baà ní ìwà
Káti ìdí mú igi gùn kí ara kólè baa rọ ni
Adífá fún Ẹ̀rìndínlógún oródù tí wón n bá ara wọn rìn tí inú wọn kò konú
Àfi àìmọ̀ ìwà hù wọn ni.
Ẹni iwájú di ẹni ìkẹyìn
Àfi àìmọ̀ ìwà hù wọn ni...
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní, ojú ọ̀run tó ẹyẹ fò láì f'apá kanra, bẹ́ẹ̀, ni iyẹ̀wù kótópó le gba ẹgbẹ̀rún èèyàn tí ìfẹ́ bá ti wà. Ènìyàn rí ojú, Aálà (Allah) ló rọ́kàn kóówá wa.
Ṣé ọ̀run ló mẹni tí ó là, bí àwọn àgbà ṣe é wí, ìdájọ́ ẹ̀dá kan kò sí lọwọ adáríhurun, àti pé káàkiri àgbáyé tí èdè kò ti papọ̀, ni àṣà kò papọ̀, tí ẹ̀sìn kò sì jọra wọn, njẹ kò ti wá di kóńkó jabele bí? Kí oníkálukú o máa ṣe tiwọn.
Ní àsìkò ìpolongo ìbò, ní èyí tó sójú mi kòró, ni àwọn asíwájú elẹ́sìn ìbílẹ̀ ti ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn Olùdíje gbogbo (àti Gómìnà Ṣèyí Mákindé pàápàá) pé kí wọn o gba ọ̀rọ̀ àwọn yẹ̀wò, kí wọn o jẹ́ kí àyájọ́ ìṣẹ̀se náà ó máa wáyé gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe lùú lóǹtẹ̀ fún àwon ẹlẹ́sìn yókù lórílẹ̀ èdè àti ìpínlẹ̀ yìí, wón ni èyí yó ṣe àfihàn pé ìjọba kò fọwọ́ rọ́ àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ sẹ́yìn àti pé bákan náà lọmọ gbogbo ẹ̀sìn sorí lọ́wọ́ ìjọba.
Ní Ọjọ́bọ̀ ọ̀ṣẹ̀ tó kọjá yìí ni àwọn Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lu ogúnjọ́,oṣù Ògún(oṣù kẹjọ) lóǹtẹ̀ gẹ́gẹ́ bí *Àyájọ́ ìṣẹ̀se, ní èyí tí yó máa jẹ́ ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ fún gbogbo òṣìṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí o ṣe wà nínú àwọn àyájọ́ ọjọ́ ọdún àwọn ẹ́lẹ́sìn yókù.
Ǹjẹ́ Ṣèyí Mákindé kọ́ ló yẹ ká máa pè ní "Ìránṣẹ́ Àlàáfíà bí? Ẹni tí ó ń wá ìrẹ́pọ̀ láàárin gbogbo ẹlẹ́sìn ilẹ̀ yìí, tí kò sì ṣetán láti pọnmi òkè rú todò. Síwájú àsìkò yìí ló tí kọ́kọ́ pín ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àṣà àti ìrìnàjò afẹ́ sọ́tọ̀, o ṣe é ní Dòdóńdáwà kúrò lára ilé iṣẹ́ ètò ìròyìn, eléyìí tí kò tíì wáyé ní ìpínlẹ̀ kankan ní orílẹ̀-èdè yìí, tó sì fi Ọ̀mọ̀wé Abdulwasiu Adéwálé Ọlátúbọ̀sún ọ̀jìnmì nípa ètò àṣà ṣé alákòóso ẹka ilé iṣẹ́ ọ̀hún, Ọmọ Mákindé ní ó di dandan, àṣà Yorùbá kò gbọdọ̀ parun.
Bí gbogbo ẹlẹ́sìn àbáláyé ìpínlẹ̀ yìí ṣe ń kan sáárá sí Gómìnà Mákindé pé ó fọmọyọ, pé ó ti fi gègé wúrà kọ orúkọ ara rẹ sínú ìwé ìtàn rere ìpínlẹ̀ yìí, àti pé títí láé làwọn ó máa rántí Gómìnà tó fiyùn àyájọ́ yìí lọ́lẹ̀, láti ọdún gbọọrọ tí àwọn ti ń ké gbàjarè, bẹ́ẹ̀ náà ni Gómìnà Ṣèyí Mákindé àti ìjọba ìpínlẹ̀ yìí ń kí wọn kú ọdún tí wọ́n sì ń gbà wọ́n nímọ̀ràn pé kí wọ́n ṣe ọdún níwọ̀ntún wọ̀nsì, kí wọn ó ṣe ohun gbogbo ní ìbámu pẹ̀lú ètò ìjọba, kí wọ́n má ṣe gùn lé ètò tàbí ìlànà tó lè da omi Àlàáfíà ẹ̀sìn tó ti ń tòrò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ rú, Kí wón fi àkókò àyájọ́ ọdún náà máa wúre Àlàáfíà, Ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè fún ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lápapọ̀.
Láti Ọwọ́:
Ayélabégàn Akínkúnmi Abbas
Ọ̀kan gbòógì nínú ẹgbẹ́ GSM ADVOCATES
Ìjọba Ìbílẹ̀ Ìwọ̀-Oòrùn Ọ̀yọ́
08134856062