03/10/2025
Abúlé Ọ̀pẹ̀rẹ̀kẹ́tẹ̀ fún fíìmù àti Ibi Ìtura jẹ́ ibùdó gbogbonìṣe. Èyí sì jẹ́ ti Délé Òdúlé, ẹni tí o jẹ́ ojúlówó ọmọ bíbí ìlú Orù Ìjẹ̀bú, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Gẹ́gẹ́ bíi igi Ọ̀pẹ tí máa ń rúwé, tí ẹ̀ka rẹ̀ máa ń yọ èso tuntun ní gbogbo ìgbà, Délé Òdúlé tí fi ìdí ipa rere lélẹ̀ nínú àṣà àjogúnbá.
Lọ́nà tí ó ṣe é mú yangàn, Délé Òdúlé ti ṣe àkójọ àwọn ohun àjogúnbá Yorùbá, Àṣà, ati àwọn ohun ìṣàmúlò fún èrè tíátà lọ́nà tí ó gbámúṣé, tí ó sì tún pegede.
Fún ìdí kan pàtàkì la ṣe fi idi Abúlé Ọ̀pẹ̀rẹ̀kẹ́tẹ̀ fún fíìmù àti Ibi Ìtura sọlẹ̀. Èyí ni láti ṣe atọ́nà àṣà Yorùbá tó múná dóko, àwọn ìtàn ìwáṣẹ̀, ohun èlò ìṣeré àti ìmọ̀ ìrandíran. Ibùdó mérìíyìírí yìí wà fún ṣíṣe àwárí imọ ẹ̀kọ́, ìrìn àjò afé tó jẹ́ mọ àṣà, ati ṣíṣe ìpàtẹ̀ ohun èlò ìṣeré, ní fífi ohun àtijọ́ ṣe àfiwé ohun òde òní.
Bi ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, ọ̀pọ̀ nǹkan ni kò ì tí ì fi ojú hàn gbangba lábẹ́ àwọn ohun iṣẹ́ àkànṣe, àmọ́ ibùdó yìí ti ṣàfihàn àwọn ohun amúnilọ̀kan nípasẹ̀ àyíká rẹ̀ tí ó dára.
Ọjọ́ tí a kò lè gbàgbé ni ọjọ́ tí ògbóǹtarìgì òṣeré, Táíwò Ìbíkúnlé- eni tí ó mọ tinú-tòde ojú ìwòran amóhùnmáwòrán, tí ó sì gbóná nínú ìtàn sísọ - pẹ̀lú àwa ọ̀jọ̀gbọ̀n akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àti olùkọ́ ẹ̀kọ́ tíàtà pẹ̀lú àṣà ṣe àbẹ̀wó sí Ibùdó Ọ̀pẹ̀rẹ̀kẹ́tẹ̀ fun fíìmù àti Ibi Ìtura. Tayọ̀ tayọ̀ la fi rìn yíká gbogbo inú àti òde ibùdó àṣà yìí, a ri ẹwà rẹ̀ bí ó ti tàn nípa bíbù kún ipa ti ìṣe àwọn Yorùbá ń kó nínú ohun ìdánimọ̀ wọn.
Láìpẹ́, ni ìgbà tí àkókò bá tó, Ibùdó Ọ̀pẹ̀rẹ̀kẹ́tẹ̀ fún fíìmù àti Ibi Ìtura yìí yóò dúró tayọ, nínú ìṣàmúyẹ, àfojúsùn àti ìfarajìn á di ààyè ńlá tí àṣà ti gbayì, ti iṣẹ́ ọnà yóò ti máa gbèrú, tí a ó sì ti máa mọ iyì àwọn ìtàn ìwáṣẹ̀, tí ìgbélárugẹ àṣà yóò ti jẹ́ ohun ìwúrí fún àwọn ìran tí ó ń bọ̀.
À ń pe gbogbo ènìyàn láti kópa nínú ẹwà àti ohun rere tí kò nípẹ̀kún yii.
Ọ̀-PẸ̀-RẸ̀-KẸ́-TẸ̀!
Igi ọ̀pẹ tí ó ní ọlá - èyí ti a bùkún láti òkè wa, fún síso èso lọ́pọ̀lọpọ̀, fún epo lónírúurú, fún èròjà oúnjẹ tí ó dára, àti lílo fún òrùlé.
Ẹ fẹ́ràn wa, kí ẹ d'ara pọ̀ mọ́ wa, kí ẹ sì má bá wa kálọ l'órí ìtàkùn wa l'óríì Facebook, Instagram, TikTok, YouTube àti Threads.
(Like, follow and interact with us via Facebook, Instagram, TikTok, YouTube and Threads)
EMAIL - [email protected]
TEL: +234(0)8120304915
Ẹ tẹ atọ́ka http://www.xn--nwmedia-9va6u.com/ láti lọ sí orí àsíá wa lórí ayélujára. (Click http://www.xn--nwmedia-9va6u.com/ to visit our website)
***
Gbogbo ẹ̀tọ́ àti àṣẹ l'óríi àwọn àw àti fọ́nrán yìí jẹ́ ti Aródú Black Dye Núwà Media .
All rights on this content belong to Aródú Black Dye (Susan Jesugbemi Awosoga) & Núwà Media .