Aremu Akekaka

Aremu Akekaka Orisun Iroyin ti ko ni Abula

Ètò ìsejọba ààrẹ Bọ́lá Ahmed Tinúbú pé ọdún méjì lónìí....Báwo lẹ ṣe rí ìsèjọba yí sí?
29/05/2025

Ètò ìsejọba ààrẹ Bọ́lá Ahmed Tinúbú pé ọdún méjì lónìí....

Báwo lẹ ṣe rí ìsèjọba yí sí?

NJẸ́ Ẹ TI GBỌ́!!!Wípé láti ọdún 2026 tó nbọ̀ yí, ìdánwò WAEC ati NECO ni yó maa wáyé lórí ẹ̀rọ kọ̀npútà.Mínìsítà fún ẹ̀t...
29/05/2025

NJẸ́ Ẹ TI GBỌ́!!!

Wípé láti ọdún 2026 tó nbọ̀ yí, ìdánwò WAEC ati NECO ni yó maa wáyé lórí ẹ̀rọ kọ̀npútà.

Mínìsítà fún ẹ̀tò ẹ̀kọ́ Dr. Tunji Alausa, pẹ̀lú àtìllẹ́yìn Àarẹ Bọla Ahmed Tinubu fi ọ̀rọ̀ yí léde lánàá. Ó ní ìlànà tuntun yìí ni yó mú àdínkù bá bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ se máa n se màgò-mágó nínú ìdánwò wọn.

Alausa tún sàlàyé wípé, ìlànà tuntun yíì ni yó mú ìrọ̀rùn bá bí a se n se ìdánwò nílẹ̀ yí. Àti wípé yó jẹ́ ká le mọ akẹ́kọ̀ọ́ tó yanrantí lẹ́nu ẹ̀kọ́ rẹ̀.

Ètò yí jẹ́ ọ̀nà láti mú ìgbà ọ̀tun dé bá ètò ẹ̀kọ́ lórílẹ̀èdè wa.

27/03/2025

IRU KILELEYI BAYI 🙆🙆🙆

Sebi iya gbogbo eniyan l'Orileede Naijiria ni iyawo Aare yẹ ko je, sugbon Oro ko ri bẹẹ rara o nigbati iyawo aare, Oluremi Tinubu se abewo si ọgba ile Ẹko awon Nọọsi to wa ni Agbor, nipinlẹ Delta.

Bi adari eto se n korin lati mu ori iyawo aarẹ wu wipe,
"Oluremi Tinubu iya wa re o
seni awọn akẹkọọ nọọsi na ndahun wipe,
"iya tiẹ nikan nio, kii se iya tiwa...

Ẹ GBAMI KẸ 😀😀😀

Naijiria gbodo gbo ewuro soju Zimbabwe lale oni...Ki ni eyin lero pe boolu na yo yori si loni?
25/03/2025

Naijiria gbodo gbo ewuro soju Zimbabwe lale oni...

Ki ni eyin lero pe boolu na yo yori si loni?

20/03/2025

Sebi Ori ti yo gbeni,
Ohun ni gbalawo ire koni.

Omodekunrin yi a maa ka iroyin lati fi sefe tabi sere, lai mo wipe Olodumare ti setan lati gba ibe lana fun un.

Nibayi, Oriyomi ti fun un niwe igbanisise re, bee lotun maa lo sile Eko ofe.

ORI MI JOWO GBEMI PADE OLOORE MI

20/03/2025

OJUMO IRE NI KO MO WA LONI O 🙏🙏🙏🙏🙏

Musulumi ngbaawe, Kristiani naa ngbaawe .... Lati ri ounje aro ati t'osan ra je bayi wa nira gbaaaa!!!E jowo, igba wo la...
19/03/2025

Musulumi ngbaawe, Kristiani naa ngbaawe ....

Lati ri ounje aro ati t'osan ra je bayi wa nira gbaaaa!!!

E jowo, igba wo lawe maa tan?

Igbakeji are tele ri lorileede yi, Ojogbon Yemi Osinbajo se ajoyo ayeye orikadun ololufe re Dolapo Osinbajo.Gege bi ohun...
15/07/2024

Igbakeji are tele ri lorileede yi, Ojogbon Yemi Osinbajo se ajoyo ayeye orikadun ololufe re Dolapo Osinbajo.

Gege bi ohun to Osinbajo fi soju opo ibanidore re, o ni ayeye eyi dun mo ohun ninu pupo nitori Dolado je obinrin rere lodede oko, ololufe tooto, oninire ati oniwa tutu bi adaba ni.
O ni idi niyi ti ohun se fi awon aworan kan to rewa to se iyebiye si ohun sita

A ki mama Osinbajo ku ayeye orikadun o

Se aye jije tun ni eleyi naa bayi abi kinla!
11/07/2024

Se aye jije tun ni eleyi naa bayi abi kinla!

Ope oooo!!!Ile ejo giga ti orileede Yi ti pase fun awon gomina lati jawo ninu eto isuna ijoba ibile leye-o-soka.
11/07/2024

Ope oooo!!!

Ile ejo giga ti orileede Yi ti pase fun awon gomina lati jawo ninu eto isuna ijoba ibile leye-o-soka.

ẸNIỌLA AJAO TỌRỌ AFORIJI LỌWỌ GBOGBO ENIYANOsere binrin onitiata ni Eniọla Ajao ti bọ sita gbangba lati tọrọ aforiji lọw...
29/03/2024

ẸNIỌLA AJAO TỌRỌ AFORIJI LỌWỌ GBOGBO ENIYAN

Osere binrin onitiata ni Eniọla Ajao ti bọ sita gbangba lati tọrọ aforiji lọwọ gbogbo eniyan nipa asise to se nibi ifihan fiimu rẹ tuntun to sẹsẹ se.

Ninu eto naa ni wọn ti mu awọn meji ti imura wọn jọju julọ (ọkunrin kan ati obirin kan). Ohun to wa mu inu bi ọpọlọpọ ọmọ orilẹede yi ni wipe, lẹyin ti wọn ti mu ọkunrin kan ti imura rẹ dara ju, kaka ki wọn mu obinrin sekeji, se ni wọn lọ kede Bobrisky to jẹ ko sọkunrin ko sobinrin. Igbesẹ yi mu inu bi ọpọlọpọ eniyan paapa julọ awọn obinrin to wa nibi eto naa. N se lo dabi wipe wọn koyan wọn kere pẹlu bi wọnse mu Bobrisky.

Ẹniọla Ajao to jẹ ẹni to ni fiimu yi ti wa jade sita lati tọrọ aforiji lọwọ gbogbo awọn eniyan, koda o sunkun lori foonu, O ni ki wọn jọwọ dariji oun ati wipe asise bayi ko ni ọga.

Ẹniọla wa rọ gbogbo eniyan lati jọwọ jade sita lọ wo fiimu yi loni ni awọn ile sinima gbogbo.

ẸJỌWỌ Ẹ JẸ KA LỌ WO FIIMU YI LATI SE ATILẸYIN FUN ỌMỌBINRIN YI.

OSINBAJO FI IKINI RANSE SI TINUBUIgbakeji aare tele ri lorilẹ-ede yi ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo ti fi ikini ransẹ si aarẹ Bọl...
29/03/2024

OSINBAJO FI IKINI RANSE SI TINUBU

Igbakeji aare tele ri lorilẹ-ede yi ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo ti fi ikini ransẹ si aarẹ Bọla Ahmed Tinubu fun ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ to maa n waye ni ọjọ kọkandinlọgbọn osu kẹta gbogbo ọdun.

Osinbajo gbadura fun aarẹ wa wipe ki Eledumare jọwọ ran wọn lọwọ lati le se aseyọri nla ti yoo mu itura ba gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria.

Ẹ BAWA FI IKINI RANSẸ SI AARẸ WA O 👏👏❤🍚🍴🎤❤

Address

Ikeja

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Aremu Akekaka posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Business

Send a message to Aremu Akekaka:

Share