16/07/2025
ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KẸRÌNDÍNLÓGÚN OṢÙ KÉJE ỌDÚN 2025
1. ÀÀRẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ ÀTÀWỌN ADARÍ ORÍLẸ̀ ÈDÈ ÁFRÍKÀ GBOGBO TI DÁGBÉRE FÚN ÀÀRẸ TẸ́LẸ̀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TÓ DI OLÓÒGBÉ, AJAGUNFẸ̀YÌNTÌ MÙHÁMMÁDÙ BÙHÁRÍ PÉ Ó DÌGBÓṢE LÁSÌKÒ ÈTÒ ÌSÌNKÚ TÍ WỌ́N ṢE FÚN LÁNÀÁ NÍ DAURA
2. OLÓYÈ ÀGBÀ KAN TÓ TÚN JẸ́ OLÙDÁSÍLẸ̀ ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍGA ALÁDÀNÍ AFẸ́ BABALỌLÁ TI SỌ̀RỌ̀ JÁDE PÉ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI PÀDÁNÙ ÈNÌYÀN TÓ YÀTỌ̀, OLÙFARAJÌN, ỌMỌLÚWÀBÍ TÍ KÒ LÁFIWÉ TORÍ PÉ ÀÀRẸ TẸ́LẸ̀ TÓ DI OLÓÒGBÉ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, AJAGUNFẸ̀YÌNTÌ MÙHÁMMÁDÙ BÙHÁRÍ ṢIṢẸ́ TAKUNTAKUN LÁTI KOJÚ GBOGBO ÌWÀ ÌBÀJẸ́ TÓ Ń ṢẸLẸ̀ LÁWỌN Ẹ̀KA ÈTÒ ÌJỌBA LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ
3. ÀWỌN ALÁGBÀTÀ EPO KÉ GBÀJARÈ SÍTA FẸ̀HỌ́NÚHÀN LÁTARI BÍ OLÙDÁSÍLẸ̀ ILÉ IṢẸ́ DANGOTE, ALIKO DANGOTE ṢE SỌ PÉ ÒUN MÁA GBÉ OWÓ AFẸ́FẸ́ ÌDÁNÁ WÁLẸ̀
4. ÀGBARÍJỌPỌ̀ ẸGBẸ́ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN TI SỌ PÉ ÀWỌN Ò NÍ PADÀ SẸ́NÚ IṢẸ́ BÍ ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN LÁBẸ́ ÌṢÈJỌBA GÓMÌNÀ DÀPỌ̀ ABÍỌ́DÚN Ò BÁ TÈTÈ WÁ ǸKAN ṢE SÍ Ọ̀RỌ̀ OWÓ ÌFẸ̀YÌNTÌ TÍ ÀWỌN Ń JÀ LÉ LÓRÍ LÁTI ỌDÚN PÚPỌ̀ WÁ
5. ALÁKÒÓSO TẸ́LẸ̀ FÚN ÈTÒ ÌKÀNSÍRAẸNI LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, Ọ̀JỌ̀GBỌ́N ISA ALI IBRAHIM PANTAMI TI GBÓRÍYÌN FÚN ÀÀRẸ ÀNÁ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TÓ DI OLÓÒGBÉ, AJAGUNFẸ̀YÌNTÌ MÙHÁMMÁDÙ BÙHÁRÍ PÉ ỌMỌLÚWÀBÍ ÀTI ÈNÌYÀN TÍ ÌGBÉ AYÉ RẸ̀ WU ÈNÌYÀN NI
6. OLÓKOÒWÒ TÓ LÓWÓ JÙ LỌ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, ALIKO DANGOTE TI RỌ GBOGBO ÀWỌN BỌ̀RỌ̀KÌNÍ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LÁTI MÁA DÁ IṢẸ́ SÍLẸ̀ KÍ WỌ́N SÌ MÁA ṢE ÒWÒ WỌN LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ KÍ WỌ́N YÉ LỌ́ SÍ ILẸ̀ ÒKÈÈRÈ
7. ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LÁTI ẸNU ALÁGA ÌGBÌMỌ̀ TÓ Ń RÍ SÍ Ọ̀RỌ̀ IṢẸ́ NÍLÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢÒFIN, AṢÒFIN BARINADA MPIGI TI SỌ PÉ ÀWỌN IṢẸ́ ÀKÀNṢE ÒPÓPÓNÀ ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ TÓ TÓ IRÍNWÓ ÀTI OGÚN NI WỌ́N TI DI PÍPARÍ LÉYÌÍ TÍ ÀWỌN KÀN ṢÌ Ń LỌ LỌ́WỌ́ LÁÀRÍN ỌDÚN MÉJÌ ÌṢÈJỌBA ÀÀRẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ
8. OLÚWÒ TI ÌLÚ ÌWÓ, ỌBA ABDULROSHEED ÀKÀNBÍ TI ṢÀPÈJÚWE ÈTÒ ÌSÌNKÚ TÍ WỌ́N ṢE FÚN ỌBA SÍKÍRÙ ADÉTỌ́NÀ, AWÙJALẸ̀ TI ILẸ̀ ÌJẸ̀BÚ NÍ ÌLÀNÀ Ẹ̀SÌN MÙSÙLÙMÍ GẸ́GẸ́ BÍ ÒMÌNIRA ÀWỌN ỌBA ILẸ̀ YORÙBÁ KÚRÒ LỌ́WỌ́ ẸBỌ RÍRÚ ÀTI ÌṢẸ̀ṢE
9. LÁTARI ÌDÁKÚREKÚ INÁ ỌBA TÓ Ń FI ÌGBÀ GBOGBO ṢẸLẸ̀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, ÀWỌN ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍGA, ILÉ IṢẸ́ ÌKÀNSÍRA ẸNI MTN, ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (NDA) ÀTÀWỌN ILÉ IṢẸ́ BÍI MẸ́RÌNDÍNLÓGÚN KAN TI BẸ̀RẸ̀ SÍ NÍ PÈSÈ INÁ MỌ̀NÀMỌ́NÁ FÚN ARA WỌN
10. IMAM ÀGBÀ MUHAMMAD MURTADHA OBHAKHOBO NÍ MỌ́ṢÁLÁṢÍ ÀPAPỌ̀ TÓ WÀ NÍ UROMI NÍ ÌPÍNLẸ̀ EDO TI KÉ GBÀJARÈ SÍTA PÉ ÒUN SAN OWÓ TÓ TÓ MÍLÍỌ́NÙ MẸ́FÀ ÀTI ÀBỌ̀ ( #6.5million) GẸ́GẸ́ BÍ OWÓ ÌDÁSÍLẸ̀ LỌ́WỌ́ ÀWỌN AJÍNIGBÉ KÌÍ ṢE ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ LÓ GBA ÒUN KALẸ̀ GẸ́GẸ́ BÍ WỌ́N ṢE Ń KÉDE Ẹ̀ KIRI
ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YORÙBÁ BROADCASTING NETWORK (YBN) LATI Ń KỌ ÀWỌN ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN OLÓJOJÚMỌ́ YÌÍ JÁDE FÚN ÌGBÁDÙN Ẹ̀YIN OLÓLÙFẸ́ WA, Ẹ ṢÉ PÚPỌ̀ FÚN ÌFẸ́ TÍ Ẹ NÍ SÍ WA, ÀJỌṢE WA Ò NÍ BÀJẸ́