
26/05/2025
Ajaabale : Seun Idosu sa kuro nile nitori iyawo re bi ibeta.....iyawo re n be ljoba ati awon egbe oloju aanu lati wa ran lowo.
Iroyin to te iroyin Yewa lowo ni pe ogbeni Agbe kan to n je Seun Idosu ti sa kuro nile nigba ti awon dokita so fun pe iyawo re to ti bimo meji tele ti tun bi meta bayi.
Osibibitu Adani kan to wa ni Agbgbe Gbokoto nilu Ilaro ni isele na ti waye ni kutukutu owuro oni ojo Aje.
Abileko Fatimoh Idosu wa n fi asikoyi ro awon oloju aanu ati ijoba ibile Guusu Yewa pelu Onorebu Ajayi to n soju agbegbe naa nile igbomo asofin ipinle Ogun ati Seneto Olamilekan Adeola Yayi lati wa ran idile oun lowo lori oro awon omo naa.