05/12/2025
Ajọ Panapana Ipinle Oyo Ṣ'e Awari Òku Ara kùnrin Ọmọ Ọdún Márundinniaadọrin Tio Jabo Si Inu Konga Ni Ọyọ
Ile Iṣe Panapana Ipinle Ọyọ ní Ọjọ́bọ sọ pé wọ́n ti ṣe awari ara ọkùnrin kan tí ó jẹ́ ọmọ ọdún Márundinniaadọrin jáde láti inú kanga j kan ní Oke-Oga Atipe, Idi-Aga, Ibadan.
Eyi ni a ṣàfihàn nínú ìkéde kan tí Olùkọ́ni Alákóso lori Atúnṣe Ẹgbẹ Ina fún Gómìnà Seyi Makinde àti Alaga ajọ naa, Moroof Akinwande, ṣe ní Ibadan.
Iroyin PUNCH Metro tún ṣe àkọsílẹ̀ pé iru ìṣẹ̀lẹ̀ ohun kan naa ṣẹlẹ̀ ní Oṣù kọkànlá ọdún 2025, nígbà tí wọ́n tún gba ara ọkùnrin ọmọ ọdún Márundinniaadọrta jáde láti inú kanga jinlẹ kan ní Odo-Ogbo, Agbègbè Oja-Agbe ní Iseyin.
Akinwande sọ pé, “A gba ipe pajawiri ní dede agogo 09:42 l’ọjọ́bọ, Oṣù Kejìlá ọjọ́ kẹrin, ọdún 2025, nípasẹ̀ ipe foonu láti ọdọ Mr Damola kan, pé ẹnikan ti ṣubú sínú kanga ní àdírẹ́sì ti a darukọ lókè. Awọn oṣiṣẹ ajọ naa, labẹ adari ACFS Bamidele Samsudeen, ni a rán lọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà lẹsẹkẹsẹ.
“Bí wọ́n șe dé síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n ṣàwárí pé ọkùnrin lootọ ní ni iṣele nàá ṣele. A gba a jáde a sì fi i lé ọwọ́ ẹgbẹ́ ọlọ́pa labẹ adarí SP Idowu láti Agugu Police Division.”
Ó bẹ̀ ẹ̀ wọ̀n araalu pé kí wọ́n yago fún ibànújẹ ọkàn àti pé kí wọ́n máa bójú tó àwọn ìṣọ́ra ààbò ní gbogbo ọjọ́.
Alaga náà tún tẹnumọ́ pé ó ṣe pàtàkì fún gbogbo ilé láti ní ohun ipa ina (fire extinguisher) láti dínà ìjàmbá ina.