AWA Obirin

AWA Obirin Contact information, map and directions, contact form, opening hours, services, ratings, photos, videos and announcements from AWA Obirin, Film/Television studio, oke odo, ilorin, Ilorin.

03/12/2015

Ifipa-ba-ni-lopo (R**e). What's ur view about it?

gbogbo eniyan eyoonigbagbo eyoatifi ipile lele Lori otitoatifi ipile lele Lori otito
30/11/2015

gbogbo eniyan eyo
onigbagbo eyo
atifi ipile lele Lori otito
atifi ipile lele Lori otito

30/11/2015

gbogbo eniyan eyo
onigbagbo eyo
atifi ipile lele Lori otito
atifi ipile lele Lori otito

27/11/2015

Eto Wa Ti O Waye Ni Ojo Ojobo Ni Dede Ago 11:30
AKORI ETO WA NI: FIFIPA BANI LOPO
Alejo wa ni: dorkita Abdul Rasheed Adekeye Odunola
Kini a n peni ifipa bani lopo?
Fifipa bani lopo je pe ki okunrin ba obirin lopo tabi ki obirin ba okunrin lopo lai se wipe o wa lati inu okan ara won tabi ti ko fun ni ase. O sese ki lokolaye fipa ba arawon lo nitori pe ko won ko fun ara won ni ase.
Ki lo sokunfa fifi ipa bani lopo
Ogun oloro ati oti mimu
Imura awon odo ode oni, yala ni ile eko giga tabi ni eko alakobere
Aikiyesi awon omo lati odo awon obi nitori ise tabi nko miran o ma n sokunfa fipa bani lo
Ero ayelujara na ma n sokunfa na, eyi ti po ni asiko wa yi
Awon ole tabi janduku, ti won ba lo jale, nibi ti wan sose yi ti won bar i obirin nibe won fi asiko yen fi pa balo nitori ohun ija ti won mu dani ti o ma je ki iru eni be fi ara lele fun won
Kini awon ohun ti o le jeyo ni ara eni ti a se iru eyi si yala nipa ti ara ni tabi ti emi?
Ole jasi iku, nitori pe ipa la fi ba lopo ti onitoun na fi ipa kun agba re ki o ma ba waye. Osi le jasi ki iru eni be sese[injury] nitori oun ti o ba ri ni wakati yen ni o ma fe fi gbe ara re.
O tun le jasi kiko arun bi ti [sexual transmitted disease] ati arun ti ko gboogu nit i a n pen i AIDS
Kini igbese ti ale gbe lati dekun iwa ibeje yi ati kini imoran yin fun awon ti oti ni iriri nkan bayii ri?
Ona po…
Ki eniyan ki o to omo eniyan ni ona esin iba je kristiani tabi musulumi
Ki imura ko je imura omoluabi nibi kibi ti a b aba ara wan
Ki a ma fi enu lasan pase fun iru eni bayi, ki won ma fi won jofin ki iru iwa buruku yii le dekun

Eto wa si n tesiwaju ni ojo mejo lori akori oro yii ni dede ago 11:30 lori agbohun safefe unilorin fm 89.3
Emi ti yin toto babarinsa olubukunmi ati owadasha oluwaseyi
Ema fi ibeere yin ranse si wa ati eto ti e ba fe ki a gbe safefe fun yi

27/11/2015

awa obirin aku aro oooo

23/11/2015

kini bibeli so nipa awa obirin??

23/11/2015

AWON EROJA FUN IDILE ALAYO
AWON EROJA FUN IGBEYAWO ALAYO.
Eroja Kinni: ISOKAN.
(Orin Dafidi 133; Amosi 3:3)
Ai si isokan je ohun ti a ko le ye sile ninu idile
Sugbon isokan je ipo ni bi ti awon meji ti igbagbo
won ko tako ara pade pelu gbigba fun ara won.
Isokan maa n sele nigba ti oko ati iyawo ba pin ero
oto., iwa, tabi ete oto Sugbon ti won gba lati fi iyato
yii sile tinutinu won fun ara won lati mu ki ete ero
kan naa se nitori igbeyawo won.
Bi a se ka ninu Bibeli o fi han wa pe Olorun feran
isokan (Orin Dafidi 133:1). Eyi fi han wa pe lai wo
gbogbo ohun ti n sele, oko ati iyawo maa n se afihan
ki n kan wa leto leto ninu ile won. Ai si isokan maa n
tu ile ka Sugbon isokan maa n fun ile lookun si ni.
KINNI AWON IDI TI AEINI ISOKAN SE MAAA N
WAYE?
Awon idi wonyii ni o maa n fa aini isokan ninu
igbeyawo eyi ti Adeola Adeniyi ko ninu iwe igbeyawo
laisi wahala:
1. Iwa Eniyan ti o yato si ara won da lori ipile iriri
enikookan ninu idile ti oko ati iyawo ti wa.
2. Igbe aye sekarimi: aini isokan maa n wo inu
igbeyawo nigbati oko ba tako rira a*o igbalode eyi ti
o le ni ipalara lori oowo ile iwe awon omo. Sugbon
ti iyawo ko ri ohun ti ko dara ninu re.
3. Ife ara eni: (Esteri 1:7 - 11) wahala maa n bere
ninu ile nigbati oko tabi iyawo baro wipe oun le se
ohunkohun lai se pe won to sona.
4. Ifaga gbaga: (Esteri 1:2,5 ,8): wahala maa n sele
ninu igbeyawo nigbati oko ati iyawo ba ri ohun ti
won ni bii – owo, iwe eri, ewa – bi ohun ti won fi ju
ara won lo
5. Gbigba imoran lowo awon ti ko to (Esteri 1:13,
15).
ANFANI ISOKAN.
1. O maa n mu itesiwaju wa (Genesisi 11:5-8)
2. O maa n mu ki ota jinna si ni (Deut 32:10)
3. O maa n mu Ibukun Olorun wa (Orin Dafidi
133:3)
4. O maa n yori si ayo ati ifowosowopo (Amosi 3:3).
Ibare ninu igbeyawo seese nigbati oko ati iyawo ati
won omo ba ni, ti won si bowo fun ilana eyi ti o
ndari ona ti won fi n huwa, woso ati dojuko awon
Akoko ti onira ninu igbeyawo.
Ara ni eya orisirisi bi o se n sise sibe won n sise
papo lati mu ki ete kan na wa si imuse. Bakan naa
oko ati iyawo ti o nife igbeyawo alayo gbodo ri ara
won gege bi ara pelu eya ara orisirisi ti o nsise papo
lati mu ki ete kan wa si imuse.
Eroja keji: ITOJU.
(Efeseu 5:28 -29, 6:4)
Itoju pe fun k**e eleomiran pelu ete ati fifi ife ati
iwuri han si elomiran. Itoju ninu igbeyawo bayi se
afihan ohun ti enkeji eni nilo ati biba awon aini yii
pade. Lati mo bi a se toju ara wa, oko ati iyawo
gbodo mo pe awon aini won yato ati ona otooto ni a
le fi ba won pade;
Lakoko, e je ki a wo awon aini obinrin eyi ti oko
gbodo ba pade;
1. Obinrin nilo ife ati iwuri: Ninu iwe igbeyawo ti o
sise, Pelt so wipe obinrin kookan nilo idaniloju pe ife
oko oun je ife aisetan ati eyi ti o fi han lojoojumo.
Ohun ti eyi tumo si fun Okunrin ni pe ki won pinnu
lati fi ife ati iwuri yii sinu ise nipa rirerin, didi mora
eni, mimoriri ati fi feti sile nigba gbogbo.
2. Obinrin nilo aabo lori imi edun: Iwadi tun fi han
pe opolopo obinrin fe idaniloju pe oun gba ibi Pataki
ninu okan oko re. Pelt so wipe obinrin le so fun oko
re lati se ohun kan eyi ti o le se funrare pelu irorun.
Ohun ti eyi tumo si ni pe ki oko kookan ma fihan
iyawo re pe leyin Olorun, oun ni o tun gba ipo
Pataki.
3. Obinrin nilo imoriri fun igbiyanju (Ise)inu ile:
Iwadi se afihan pe obinrin fe ki oko re mo iriri re fun
titun inu ile se. Ohun ti awon Okunrin miran ko ka
si. Eyi tumo si pe oko gbodo maa ki iyawo re ninu
ohun “kekere: ti o ba se.
4. Obinrin nilo imoriri fun igbiyanju titun ara Re se
lati Dun – un wo: Olugbani nimoran lori igbeyawo
kan ko bayi pe obinrin nilo opolopo idaniloju pe o si
dun wo lai wo bi ojo ori re se to. Okunrin gbodo maa
mo iriri bi o se ri, a*o ati bata re.
Eko yii tun se agbeyewo lori aini imi – edun ati ti ara
ti awon awon obirin ey ti Okunrin gbodo ba pade.
Ifiyesi: E jiroro lori aini ti owo, ti ero ati ibakegbe ti
obinrin eyi ti oko kookan gbodo ni oye re ki o ba le
mo bi yoo se boju to.
Ni ona miran, obinrin kookan ti ofe lati toju oko re
gbodo koko mo awon aini Okunrin kookan.
1. Okunrin nilo owo (Ibowo fun) (Efesu 5:22) Ibowo
fun je lati moriri oun ti o je. Onimo igbaninimoran
lori igbeyawo se awari pe Okunrin nilo latari mo pe
iyawo oun bowo fun on ni ona ti iyawo naa n gba
soro, ni ona ti o ri gba wo gege bi olori ile.
Ijiroro: Se ki oko maa gba ibowo ni tabi ki o maa
bere fun?
2. Okunrin nilo gbigba iyi fun imura, agbara ati iwa
Re.
Imura tabi iriri Re: inu Okunrin maan dun ti
iyawo re ba yin iduro re. kin ni idi ti opolopo
obinrin Kristiani kii fi yin imura oko won?
Agbara: Nigbati iyawo ba se ajoyo lori oye ati
talenti oko re, aseyori lenu ise yoo po si fun iru
oko yii.
Ihuwasi: iyawo ti o ba mo riri ifarada oko re yala
ni ti wahala eto isuna ti opolo ni gbigbiyanju
lati ba aini inu aye iru oko naa pade.
Itoju se Pataki ninu idile Kristiani loni nitori orisirisi
ogun ni o wa fun oko ati iyawo Kristiani kookan eyi
ti o le nipa lori ife Akoko won. A maa mu ife dara si
nigba ti oko ati iyawo ba mo awon aini won ti won
si baa pade pelu iwa pele.
Eroja Keta: IFIFUNNI.
(Romu 8:32; 11:35)
Odi igbekele maa n wo lule ninu ilekile nigba ti oko
tabi iyawo ba lahun. Ififunni je ajosepo igbeyawo eyi
ti o pe fun fifi ohun ti oko tabi iyawo ba ni sile ki o
ba le ba aini ara won pade ati leyin naa gbe idile
alayo kale. Ni oro miran, igbeyawo pe fun ififunni.
Ni idi ti ififunni se se Pataki ninu igbeyawo Kristiani?
O se Pataki nitori ajosepo ati ifara eni sile ninu igbe
aye igbeyawo toka fun aye ajosepoti o wa laaarin
Kristi ati Ijo. Jesu, oko iyawo fi gbogbo re sile de oju
iku ki o ba le se afihan ife Re si Ijo (Iyawo). O tun
toka si pe oko ati iyawo ti se awari pe ohun ini won
ni a fi fun won lati mu ki idile won dagba. Bakan naa
ififunni pelu ifarajin se afihan pe oko ati iyawo ti ri
ara won bi ara kan ti ko se pinya bayi, ohun ti won
ni je ti awon mejeeji
Awon Ohun ti o ye ki oko ati iyawo fi fun ara won.
Ko si oko ati iyawo ti ko ni ohun kan ti oye ki ofi sile
lati mu ki igbeyawo won dara si. Die lara awon ohun
ti o ye ki awon oko ati iyawo pin pelu ara won ni:
1. Akoko / Ifetisile: Opolopo Akoko maa n pese
anfani lati fikunlukun tabi pin isoro, ero, eru papo
ati salaye aigbora eni ye funra eni.
2. Owo: owo maa n pese anfani lati ba aini ti isuna
ti enikookan pade
3. Ara: Se e maa n fi ara yin sile lati te ife ibalopo
lorun fun ara yin?
4. Ero / Oro: Se a maa n ronu papo tabi fun ara yin
ni imoran eyi ti o le ran ipinnu idile wa lowo?
5. Ebun: Se a maa n fi ebun fun ara wa alsiko ojo
ibi, ayeye ikeko jade abbl.
Olorun je olufifunni. O se agbekale igbeyawo ki a ba
le mo bi a se n pin gbogbo nkan pelu ara wa. Aami
miran fun idile Kristiani ni lati fifun elomiran.
1. Fifi fun Olorun.
2. Fifi fun awon alaini ati opo.
3. Fifi fun awon omo yin.
4. Fifi fun awon omo alailobi.
5. Fifi fun awon oniwaasu.
6. Fififun ise Ihinrere.
IFIYESI.
1. Owe 31:16, 20 se apejuwe obinrin gege bi
olufifunni. Kin ni idi ti o fi maa n soro fun opolopo
obinrin lati fifun oko won ati awon oko lati fifun
awon iyawo won?
2. Kinni ipa ti iyawo / Oko ti o ba je ahun maa n ni
lori awon omo?
Eroja Kerin: ITERIBA
(Genesisi 3:16, Efesu 5:21, Romu 10:3)
Iteriba kii se siso ohun ti eniyan je nu tabi maa
gboran bi afoju si awon alase. Itumo iteriba ninu
majemu titun je nigba ti “eni kookan ba teti si ero
tabi ife ara won” tokantokan nigba ti ero won ba
tako ara won. O tumo si pe iteriba ninu igbeyawo
Kristiani ko so oko di olori nibi ti yoo ti maa pase ti
iyawo re yoo si teriba bi eru (ati ni idakeji pelu)
(Efesu 5:21). Gege bi Pelt se ko, Jesu Kristi teriba si ife
Baba re sugbon eyi ko je ki o je alaitegbe nigbati o
teriba.
Kinni awon ise Pataki iteriba.
Pataki iteriba ninu igbeyawo fi idaniloju idari Olorun
ninu ile eyi ti o maa n mu ki ibare wa. (Korinti kinni
11:3,8,9,11,12). Ete miran ni ki iyawo le ri iteriba bi
iwa eyi ti o n fi ibowo fun Olorun han.
Bawo ni eyi se n sise?
1. O maa n sise nigati awon took –taya ba ri ara
won gege bi egbe niwaju Olorun pelu eto lati se ipinu
pelu ogbon.
2. O maa n sise nigbati took –taya ba dowo fun ero
ara won Sugbon ti won ko ko maa figagbaga.
3. O maa n sise nigbati iyawo ba n mo pe oko ohun
nife, o si gba oun. (Efesu 5:25)
Tani oko ati iyawo ye ki o teriba fun?
Amin Ife Olorun Akoko ninu igbeyawo ni iteriba si ife
Olorun (Deuteronomi 6:5). Won gbodo tun bowo fun
awon adari emi, ijoba, awon obi ati fun ara won.
(Efesu 5:21)
Iteriba maa n fi aaye biba ara eni soro daa sile at
leyin naa se ipinu ti o mogbon wa ati eyiti to je okan
lara iwa rere fun idile alayo.
IFIYESI:
1. Jiroro lori awon idi ti aini iteriba se wa ninu idile
Kristiani ati ona abayo.
2. Kinni awon ipa ti aini iteriba fun ara eni ns e wa
laarin oko ati iyawo.
Eroja Karun: IBARE NINU ORO.
(Kolose 3:12 – 17, 4 – 6)
Opolopo oko ati iyawo ni won nife lati maa pin ohun
ti o nse won ati aini won pelu ore, awon ti a jo n sise
ati awon ana won ju ki won pin pelu enikeji won lo.
Sugbon Gary Smalley, eni ti o je onimo ninu
igbeyawo so wipe ibare ninu oro le wa ninu
igbeyawo nigbati oko ati iyawo ban pin aini ati ohun
ti n won n la koja pelu ara won. O je okan lara
kokoro si ifarada ninu igbeyawo. Ki oko ati iyawo le
ri ara won bi ore ti o se gbekele ti won le ba soro.
Oro siso papo eyiti o jinle ni awon ete yii:
1. O maa nfaye sile fun sisoro ti odan moran lori
ohun ti o jeyo ki oye ba le wa.
2. O maa n jeki igbagbo odi di mimo si ara eni.
3. O maa n je ki adura won di didahun. Idile ti o ba
n soro papo maa bo lowo gboyi soyi.
4. O maa nje ki awon omo, ana ati adugbo bowo
fun awon ati igbe aye won je eko fun elomiran.
Bawo ni sisoro papo se le sise
Awon ona ti oko ati iyawo ti o fe ayipada ninu bi
won se n ba ara won soro le lo eyi.
1. ki won gba ara won gege bi ore.
2. Feti silesi awon ami ibara – eni – soro si ara eni.
Awon itumo miiran le wa ninu ohun ti o n so bi
ihuwa, a*o ati iri wa.
3. Maa lo oro rere. Ma maa siregun tabi bu eebu.
Awon oro nipa awon Okunrin ati obinrin alagbara
fihan pe oro ti awon enikeji won so lati gba won
niyanju lo so won di alaseyori.
4. Maa fi imi edun re ti ko dara han ninu ife. Faye
gba Emi Mimo lati kapa ibinu ati ikoro re ki ibinu
ati ikoro ma baa ma dari re.
5. Maa bere ibeere. Ma fa seyin nigbati e ba ja. Maa
lo oro bi “awa” dipo “iwo” lati toka alebu
enikeji re.
Idile Kristiani gbodo faaye gba Emi Mimo lati je ti
won. Soro daada pelu ife ati pelu otito inu. Won
gbodo faaye gba siso ero won lai si iberu lori ohun
gbogbo ti oba jeyo. Awon oko gbodo maa soro
pelepele pelu awon aya won. Awon omo gbodo kopa
ninu adura ati ipinu idile. E ma gba awon omo
niyanju lati maa so ero won aliberu, eyi yoo mu ki
won ni igboya. E maa ko won ni ona ti won yoo lo ti
won ba dagba won yoo le soju yin ati Olorun daadaa.
(Owe 22:6). E jowo asise yin, e darijin ki e si maa
gbadura fun arayin. Ni sise eyi igbekele ati isokan
yoo wa ninu idile .
Ona ti o sise julo ni biba ara eni soro ni bi a se n
gbe igbe aye wa. Ise wa soro ju oro enu wa lo.
IFIYESI.
1. Kinni idi ti opolopo oko ati iyawo kii se ba ara
won soro nigba ti won ba ja?
2. Kinni ipa ti eyii maa n ni ati ona abayo.
Eroja kefa: IDARIJIN.
(Matiu 6:12 – 15, Isaiah 43:25 – 26)
Itumo idarijin Akoko ni lati tu eniyan sile. Eyi tumo si
pe nigba ti oko ati iyawo ba ni ikoro si ara won, oko
ati iyawo so ara won pelu okun ni yii. Ija je ohun ti a
ko le ye sile ninu igbeyawo. Sugbon o maa n jeki oko
ati iyawo pa ara won alara. Eyi si le je okankan ninu
oko tabi iyawo fi ibinu pamo si ara won eyi si le je ki
pipari ija soro.
Bawo ni aini idarijin se n sise
Ona ti aini idariji se nsise ninu igbeyawo ni ngbati
yala oko tabi iyawo ba n dibon bi eni ti ko ni ipalara
gege bi esi si ija ti won ja Sugbon ti on se afiha re
ninu ise re nipa.
1. Bibinu lori imubinu kekere kan.
2. Siseregun
3. Fifa seyin tabi didake
4. Aifowosowopo
5. Iwa ti ko je itewogba
6. Ikosile
Ipa yii maa n mu ki aifokan bale wa ninu ile.
Bi idariji se n sise
Idariji maa n wo ajosepo san. Gary Smalley, Onimo
ninu igbani nimoran lori igbeyawo se afihan awon
igbese die yii:
1. Faaye gba igbonara re ki o tutu lati gba ogbon ati
oye si isoro naa ki e to jiroro le lori.
2. Faaye gba eni ti a se lati banuje. E soro nipa sioro
naa fun ara yin ki e fi gbogbo re sile fun Oluwa.
3. E wa eko ninu ese naa ki e maa ba tun se asise yii
mo .
4. E tu eni ti o ba se yii sile ju ki e gbiyanju lati
gbesan lo (Romu 12:19). E gbadura fun ookun
Olorun lati le je ki e laannu eni ti o se yin.
5. E toro aforiji lowo ara yin. E wa awon ona ti o le
se iranlowo ni wiwo eni ti o se yan san.
Awon ona yii wa fun eniti o se ti osi gba a si asise re
ati ti o si setan lati se atunse. Eni ti a se gbodo mo pe
a ti dari ese re jin nigba kan ri nipase Olorun.
IFIYESI.
1. Kiyesi esekese eyi ti o n fi pamo fun oko tabi
iyawo re ki osi jewo re pelu oye Olorun loni.
2. Eyin omo, se e ni ohunkohun ninu okan si awon
obi yin? E so loni ki e si darijin won Olorun yoo
si sure fun yi.
3. E gbadura fun awon eniyan ti o se yin Sugbon ti
won ko beere fun idarijin. Bi o ba ssese e so fun
ki e si darijin won.
Eroja keje. ADURA IDILE.
(Dueteronomi 6:4-9; Orin Dafidi 1:2 – 3)
A maa n saba ro pe aseyori maa n wa ninu oko tabi
iyawo ti o rewa, ise ti o dara, ore, owo ile tabi ipo.
Otito ni pe nigba ti ipenija ba de awon nkan yii ko le
duro ayafi Olorun ti o je orisun agbara ifarada
(Matiu 6:9 -21). Nitori naa, a nilo lati wa agbara
atoke yii eyi ti yoo maa so igbeyewo wa ji.
Adura idile bayi maa n pese aaye fun Olorun Eleda
Eni ti o da igbeyawo sile lati soro ba wa wi, bukun
ati to oko ati iyawo ati awon omo sona lojoojumo. Ko
si eni ti o koja asise.
Idi ti adura idile fi se Pataki
1. Igbeyawo kii se ero eniyan (Genesisi 2:18 -23)
2. O maa n daabo bo idile lowo igbogun nitori ota
maa n wa ona lati tu idile ka. (Genesisi 3).
3. O maa ntun okun oko ati iyawo ati awon omo se
lati ni fe ara won lojoojumo (Isaiah 40:31)
4. O maa n fun idile ni oye ilana Olorun titun fun
ojo kookan (Deuteronomi 6:7 – 9)
5. O maa n nipa lori awon omo lati ni igbagbo ninu
Olorun ni ibere aye won (Orin Dafidi. 71:18,23)
Bi adura idile se e le sise.
1. E ji laaro kutukutu lati bu ola fun Olorun fun ojo
titun.
2. E sin Olorun ninu orin.
3. Elo akoko pelu Olorun ni kika oro Re.
4. Sasaro lori oro Olorun, ki e si pin itumo re pelu
ara yin.
5. E dari idile lati ko ese Bibeli sori.
6. E ni iyara eni sapakan opin ose.
Idile ti o ba gbadura papo yoo wa papo. Idile kookan
nilo iwalaaye Olorun lojoojumo lati koju ipenija
ojoojumo
Koko adura
1. Oluwa ran mi lowo lati mu ohun ti o ti seto fun
mi ati enikookan ninu idile mi se ni oruko Jesu
2. Ran wa lowo gege bi idile lati ma sina.
3. Oluwa ran wa lowo lati pa ogun ini wa mo eyi ti
o je fifesemule ninu Re.
A tee eko yii jade lati le ran Idile Omo Ijo yii kookan
lowo, ki o si le e ro Idile kookan lagbara sii. Nitori
naa bi E ti n lo o, E ko eko, ki E si gba ipenija ninu re
lati fi se atunto eeto Idile yin. Esu atomogun re ko ni
ri aye ninu Idile yin. Leyin aye yii, eto Idile wa ko ni
mu wa sina Ijoba Olorun.

Address

Oke Odo, Ilorin
Ilorin

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when AWA Obirin posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Share