14/05/2025
Ileeṣẹ redio ti pọ ju n'Ibadan, o yẹ ki ijọba wa nnkan ṣe si i- MC Swagger
Olujabo iroyin Ọlawale Ajao,
Nitori bi awọn eeyan ṣe n da ileeṣẹ redio silẹ kaakiri ṣaa ni ipinlẹ Ọyọ, alaga ẹgbẹ awọn agbohunsafẹfẹ lorileede yii, iyẹn Association of Nigerian Broadcasters, ANBROAD, ẹka ipinlẹ Ọyọ, Dokita Ọpẹyẹmi Ayanrinde, ti rọ ijọba lati wa nnkan ṣe si ọrọ awọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ ni ipinlẹ naa, o ni ileeṣẹ redio to wa ni ipinlẹ Ọyọ ti pọ ju bo ṣe yẹ lọ.
Dokita Ayanrinde sọrọ yii ninu ipade to ṣe pẹlu awọn awọn oniroyin lolu ileeṣẹ ẹgbẹ naa nibadan laipẹ yii.
Iwadii fidi ẹ mulẹ pe ileeṣẹ redio to wa ni ipinlẹ Ọyọ ko din ni mọkanlelọgọta (61), aadọta (50) ninu ẹ lo si wa niluu Ibadan nikan.
Eyi lọga awọn sọrọ ipinlẹ Ọyọ, ti ọpọ eeyan n pe ni MC Swagger yii bu ẹnu atẹ lu, o ni nṣe ni kinni naa n ba iṣẹ iroyin jẹ, bẹẹ lo n yẹpẹrẹ awọn akọṣẹmọṣẹ oniroyin gbogbo.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, "nṣe lawọn eeyan kan n da ileeṣẹ iroyin silẹ ṣaa lasiko yii, ti awọn NBC, ajọ to n moju to eto igbohunsafẹfẹ naa si n fun wọn niwee aṣẹ, bẹẹ, omi-in ninu awọn ileeṣẹ wọnyi ki i tẹle awọn ofin to rọ mọ iṣẹ yii nitori awọn oludasilẹ wọn ko nimọ nipa ofin igbohunsafẹfẹ ati itọju awọn oṣiṣẹ wọn.
"Eyi lo fa a to fi jẹ pe ọpọ ninu awọn oludasilẹ ileeṣẹ redio ni wọn kan maa n lo awọn oṣiṣẹ wọn nilokulo laibọwọ fun ẹtọ wọn ati laibikita nipa adehun to wa laarin wọn ṣaaju gẹgẹ bii agbanisiṣẹ ati oṣiṣẹ. Ko yẹ ki eyi maa ri bẹẹ lọ, a fẹ ki ijọba wa nnkan ṣe si i"
MC Swagger waa rọ awọn National Broadcasting Commission (NBC), iyẹn ajọ to n dari eto igbohunsafẹfẹ lorileede yii lati yee maa fun awọn ileeṣẹ tuntun niwee aṣẹ igbohunsafẹfẹ mọ laiṣewadii daadaa lati ri i daju pe ẹni to fẹẹ da ileeṣẹ ọhun silẹ mọ nipa iṣẹ iroyin ati eto igbohunsafẹfẹ daadaa.
Bakan naa lo rọ ẹka alaṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ ati ileegbimọ aṣofin ipinlẹ naa lati ṣagbekalẹ ofin ti yoo ṣafọmọ iṣẹ iroyin, ki ijọba le da aṣọ iyi bo iṣẹ naa ni ipinlẹ yii ati lati fopin si bi wọn ṣe n tẹ ẹtọ awọn oniroyin loju mọlẹ.