18/02/2025
Ninu apoti awọn agba
ỌṢẸ ÌYỌ́NÚ
Esuru pupa, ao gun papo mọ kanhun bilala to mu daadaa,,ao fi ọṣẹ dudu ko o, ao maa fI omi gbigbona wẹ ẹ lalaalẹ
ỌṢẸ RÍRÍṢE
Esuru pupa,ao gun pọ mọ ọpọlọpọ ọṣẹ,ao wa adiẹ pupa, ẹjẹ rẹ ni ao fi po ọṣẹ naa,ao lọ ri adiẹ naa mọ ori akitan,ao maa fi ọṣẹ naa wẹ lalaalẹ pẹlu omi gbigbona, ao fi kun bẹẹ ni ao yọ kuro, fi adura ranṣẹ ko le jẹ fun ẹ.
ASEJẸ AṢÍÍRÍ BÍBÒ TÓ JẸ́
Kidinrin maalu kan,ao ge e si ọna mẹrindinlogun, ao wa ewe tannagbowo ati itanna rẹ,ewe ajeṣẹṣẹfun, iyere mẹrindinlogun,ata ijọsi mẹrindinlogun, ao se e lepo niyọ, ao sọ kalẹ sori oṣuka, ao wa gbadura sii ṣugbọn ko le mu wa kọja aadọta naira o,kii ṣe oogun owo o,aṣiiri bibo lasan ni.lẹyin oṣu kẹta ni o tun le dan an wo.
OÒGÙN ÌSỌ̀YÈ
Ẹye awoko, eye ẹga, ewe oniyeye, odidi atare kan, jijo pọ,a maa da sinu oyin, lila ni o.
AWO IGBA ÀÌSÀN
Tagiiri kan, ao wa ge si wẹwẹ,bara kan ao ge si wẹwẹ,eepo ọsan wẹwẹ ẹru alamọ, kanhun bilala, awusa tutu, ata adayeba, jijo pọ ao da sinu omi ọsan wẹwẹ, mimu laarọ ati lalẹ.
OJÚLÓWÓ ÀGBO ÌWÒSÀN FÚN ÀFẸ́LÙ RỌPÁRỌSẸ̀
Ao wa ọpọlọpọ ewe gbaguda tutu,ewe pia(pear) tutu,ewe esuru pupa tutu, ataalẹ pupa (tumeric), ewe ọsan banbu, eepo ọsan banbu, eepo igi ati ewe koko(cocoa), kanafuru to pọ diẹ,ewe dongoyaro tutu, ao fi omi to mọ daadaa se gbogbo rẹ lagbo ti yo hoo daadaa,ao ma mu ni gbigbona ni gilaasi kọọbu kan laarọ, ati lalẹ fun ọjọ marun leralera,ao ni gburo aisan naa mọ, ẹniti ko ba tii ni rọparọsẹ naa le lo, atẹgun buruku ko nii fẹ lu wa o, awọn to ti ṣe maa gba iwosan laṣẹ Edumare.
OJÚLÓWÓ ÀGUNMU FÚN ÀRÙN ILÉ ÌGBỌ̀NSẸ̀ ỌLỌ́JỌ́ PÍPẸ́ TÓ DÁJÚ
Ko si bo ti le wu ki aisan ileegbọsan buru tabi pẹ lara to, ti o ba fi le fi agunmu yii lo ẹkọ gbigbona, o ni gburo rẹ, mọ alaafia to peye yoo si de ba agọ ara rẹ, ao wa ewe ati egbo iṣirigun gbigbẹ,ewe ati egbo agbosa, ẹfọ yanrin, ao sa ti yoo gbe,taba jukuu,ao sa ti yoo gbẹ,alubọsa aayu,ao sa ti yoo gbẹ,ao gun gbogbo rẹ kunna daadaa,ao tun fi ajọ jọ ọ,ao mo fi ṣibi imukọ ọmọ kekere kan sinu ẹkọ gbigbona laarọ kutukutuki a to jẹun,iwọ naa yoo si ri bi awọn nnkan funfun kan yoo ṣe ma jade nibi itọ rẹ, itọ naa yoo si ma run gidi gan,ma bẹru,awọn nnkan ti ko da lara rẹ ni o n tọ danu yẹn, lo leralera fun ọsẹ kan, ao tọ gbogbo rẹ danu, alaafia to peye yoo si de ba agọ ara wa, dan wo ko fun ile labọ. Yoo jẹ fun yin o.