09/02/2024
Who can relate to this?
Call Daddy when you have just 10seconds to spend, for Mummy,Wait till Weekend or Public Holidays !!!
Phone call 1:
Me: Hello Sir
Dad: Hello, How far? Bawo Ni?
Me: Mo wa okay. Bawo Ni day yin Sir?
Dad: O lo daada. Ise nko?
Me: Ise wa daada.
Mummy nko?
Dad: O wa. Just be fine. God bless you.
Me: Okay Sir.
Dad: A tun ma soro... Later.
Phone Call 2:
Me: Hello Ma.
Mum: Hello... Oko mi... Akanni omo ologun eru... (she keeps eulogising for the next 5mins)
Me:(cuts in) Mummy, shey e wa daada? Bawo Ni gbogbo ile?
Mum: Mo wa. Ko pe ti mo de lati church ani special women program, look, gbogbo yin ni mo gba'dura fun, mo ti ri'yin bo'nu eje Jesu, oju ko'ju kan koni wo'yin it shall be well with all of you.
Pastor even asked of you, we prayed for you together
Woo, Mo ri ore e kan, e Jo ma n wo pata shere Ni kekere ni. Omo iya Kayode to wa Ni...
Me: (cuts in) Mummy, ko pe ti mo d'ele lati office, O re mi, mo Fe lo rest.
Mummy: Hhaa... Pele oko mi. Shey stress office po'ju ni? Nkan ma waani oro whala ibi ise yin yi ooo,
Shey o ti jeun? Kin lo ri je bayi? Shey o lo ogun malaria yen? Neck pain yen nko? Shey ese to fi gba okuta Ni 2012 yen o ro e mo...
Me: Ko si wahala, mo ti je Noddles.
Mummy: Hhhaa, Iwo omo yi, Indomine again? !!!!, Oo'ni oro gbo, Oo'se obe ni?
Duro. Voice e lo sile... Kilode? O n bami ja Ni?
Me: Rara ma. O ti remi Ni.
Mummy: Awwww. Oya lo we, ko de lo oogun E before you sleep. And make sure you sleep on time . L'oruko Jesu, wa goke, waa de ibi giga, Owo Olorun A di E mi
Me: Amin Ma
Mummy: L'oruko Jesu, Inu rere wa ma tan imole fun e
Me: Amin
Mummy: L'oruko Jesu o Ni shi Ise se, waa ma'ri aanu gba. O Ni daran...
Won o Ni Koba e. O Ni shishe... Ishe e ko Ni baje. Oluwasegun la so e, oruko e ma ro e...
Me: Amin, Amin, Amin, Amin (Like 10 Amin, thinking she would know I was getting bored already)
Mummy: L'oruko Jesu, o Ni shubu... Ona to shi, Olorun a je ko shi dale...
Me: Amin (Talking through my nose)
Heard Dad's voice in the background
Dad: Je ki omo yi lo sun now.
Mummy: Lo sun, oko mi. L'oruko Jesu awon Angeli ma daabo bo e l'oju orun. Ti o ba ji, won o Ni fi e sile.
Me: Hello... Hello, Hello mummy. Network yi o. Hello.......(Pretending network is bad) (ends the call).
Returns from the bathroom and picks phone: 12 missed calls from mummy.
You can call Dad if all you have to be brief, Mum? Wait till public holiday
May God bless parents in their diversities. For those whose parents are gone, may God rest their souls.