18/10/2025
*ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌJỌ́ KEJÌDÍNLÓGÚN OṢÙ KẸWÀÁ ỌDÚN 2025*
1. *ÀÀRẸ ẸGBẸ́ ÀWỌN AGBẸJỌ́RÒ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, AFAM OSIGWE TI SỌ PÉ ÀJỌ ELÉTÒ ÌDÌBÒ ORÍLẸ-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ (INEC) Ò NÍ ÀṢẸ LÁBẸ́ ÒFIN LÁTI SỌ PÉ ÀÀYÈ GÓMÌNÀ KAN SÓFO LÁTÀRI PÉ Ó KÚRÒ NÍNÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ KAN LỌ SÍ ÒMÍRÀN*
2. *ILÉ ẸJỌ́ GÍGA LÓLÚ ÌLÚ WA ÀBÚJÁ TI DÁ ỌMỌ́YẸLÉ ṢÒWÒRẸ́ ÀTI ÀWỌN TÓ KÙ LỌ́WỌ́ KỌ́ LÁTI MÁ ṢÈTÒ ÌFẸ̀HỌ́NÚHÀN LÓRÍ ÌDÁSÍLẸ̀ ADARÍ IKỌ̀ TÓ Ń PÈ FÚN ORÍLẸ̀-ÈDÈ BIAFRA, NNAMDI KANU TÍ WỌ́N Ń ṢÈTÒ Ẹ̀ LÁTI WÁYÉ LỌ́JỌ́ AJÉ TÍÍ ṢE OGÚNJỌ́ OṢÙ KẸWÀÁ*
3. *ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÌTÌ TI ṢE ÌFÍLỌ́LẸ̀ IBÙDÓ TÍ WỌ́N Ń KÓ ÒÒGÙN SÍ LÁTI LÈ DÈNÀ ÀWỌN OÒGÙN AYÉDÈRÚ TÍ ỌJỌ́ TI LỌ LÓRÍ WỌN*
4. *ILÉ IṢẸ́ ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ LÓRÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI KÌLỌ̀ ÈTÒ ÀÀBÒ FÚN ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀-ÈDÈ WỌN ṢÁÁJÚ ÌFẸ̀HỌ́NÚHÀN ÀWỌN TÓ Ń BÉÈRÈ FÚN ÌDÁSÍLẸ̀ ADARÍ IKỌ̀ TÓ Ń PÈ FÚN ORÍLẸ̀-ÈDÈ BIAFRA, NNAMDI KANU TÓ MÁA WÁYÉ LỌ́JỌ́ AJÉ TÍÍ ṢE OGÚNJỌ́ OṢÙ KẸWÀÁ*
5. *ILÉ IṢẸ́ ẸBU ÌFỌPO DANGOTE TI JẸ́ KÓ DI MÍMỌ̀ PÉ ÒUN TI ṢE ÀKỌ́SÍLẸ̀ ÀWỌN ÌWÀ MỌ̀DÀRÚ TÓ TÓ MÉJÌLÉLÓGÚN LÁTI ÌGBÀ TÍ WỌ́N TI DÁA SÍLẸ̀*
6. *ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ ALL PROGRESSIVES CONGRESS NÍ ÌPÍNLẸ̀ PLATEAU TI BỌWỌ̀ LU ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ GẸ́GẸ́ BÍ ALÁṢẸ NÍNÚ ÌDÌBÒ ỌDÚN 2027 LÉYÌÍ TÍ WỌ́N WÁ KORÒ OJÚ SÍ BÍ GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ PLATEAU,CALEB MUFTWANG ṢE FẸ́ DIGBÁDAGBỌ̀N Ẹ̀ TA KỌ́ṢỌ́ SÍNÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ NÁÀ*
7. *AJÌJÀGBARA ÀWÙJỌ OBÌNRIN NÌ, TÍ Ó TÚN JẸ́ AJÀFẸ́TỌ̀ ỌMỌNÌYÀN, AISHA YÉSÚFÙ TI SỌ̀RỌ̀ JÁDE PÉ ÀÀYÈ ÀTI ÀǸFÀÀNÍ ŃLÁ WÀ FÚN ADÍJEDUPÒ ALÁṢẸ LÁBẸ́ ÀSÍÁ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ LABOUR PARTY, PETER OBI NÍNÚ ÌDÌBÒ ÀPAPỌ̀ TÓ MÁA WÁYÉ LỌ́DÚN 2027 JÚ ÌDÌBÒ ÀPAPỌ̀ TÓ TI WÁYÉ LỌ́DÚN 2023 LỌ*
8. *ÀWỌN AṢOJÚ ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ TI JẸ́ KÓ DI MÍMỌ̀ PÉ ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ Ń ṢEKÚ PA ÀWỌN ẸLẸ́SÌN MÙSÙLÙMÍ PÚPỌ̀ NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ*
9. *ỌWỌ́ ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PAA ÌPÍNLẸ̀ BAUCHI TI TẸ OKÙNRIN KÀN ỌMỌ ỌGBỌ̀N ỌDÚN TÍ ORÚKỌ̀ RẸ̀ Ń JẸ́ MAMUDA ZAKARI YAU LÓRÍ Ẹ̀SÙN PÉ Ó GÚN ỌLỌ́KADÀ KAN PA, Ó SÌ JÍ ỌKADÀ NÁÀ LÁTI LÈ RÍ OWÓ ṢE ÌGBÉYÀWÓ*
10. *ÀWỌN AGBÉBỌN ṢEKÚ PA ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ MÉJÌ NÍNÚ ÌKỌLÙ TÓ WÁYÉ NÍ ÌPÍNLẸ̀ KÀDÚNÁ*
*OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ (GLAMOURLADY)*
*LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙN-MÁWÒRÁN YORÙBÁ BROADCASTING NETWORK (YBN)*