
03/06/2025
Ojú tó bá rí òkun ti rí ọba omi, èyí tó rí ọ̀sà ti rí ọba odò, ojú tó bá rí gẹ̀lẹ̀dẹ́ ti rí òpin iran. Ijó ìbílẹ̀ Yorùbá gan-an ni a à bá máa pè ní òpin àríyá nitori pé ó dùn kọjá àlà, kò sé fi ẹnu ròyìn.
Ní ibi ÀYÁJỌ́ ÈDÈ ABÍNIBÍ ÀTI ÀṢÀ YORÙBÁ èyí tí ilé-iṣẹ́ ALAKITAN CULTURAL ENTERTAINMENT ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀, a ṣe àfihàn ijó ìbílẹ̀ Yorùbá fún àwọn mọ̀jèsín àti àwon olólùfẹ́ àṣà Yorùbá àti èdè abínibí, inú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sì dùn, ara wọ́n yà gágá bí ara a-kẹ́-kọ-sí asọ.
Èròńgbà wa láti máa mú ìdàgbàsókè bá àwọn lítírésọ̀ Alohùn Yorùbá tí ijó àjórẹ̀yìn tí ń dé bá.
Alakitan Akanbi Entertainment LTD
Alakitan Akanbi AKEWI