Clicky

Awon AKONI yoruba

Awon AKONI yoruba Contact information, map and directions, contact form, opening hours, services, ratings, photos, videos and announcements from Awon AKONI yoruba, Media/News Company, New York, New York, NY.

Operating as usual

07/29/2022

Join this Powerful family Program on the
1st - 3rd August
Theme: the Curse in the Family ( Egun to wa ninu Igbayawo)
Host by Primate Isaiah Ademiju
Don't miss it oo

04/12/2022

Lagbaye Ja Program live now

01/18/2022

Lagbaiye Ja Program live Now

01/15/2022
11/30/2021

Lagbaye Ja family Program

11/02/2021
10/19/2021

Lagbaye Ja family Program live now

09/24/2021

LA AGBAIYE JA FAMILY & RELATIONSHIP FOUNDATION
Motto: To Build A Home is Our Priority
Our little ways of Supporting Education
EDUCATION SUPPORT PROJECT PHASE 1
WATCHOUT FOR MORE.

Iyán funfun àti ọbẹ̀ Ẹ̀fọ́ Rírò tí irú wooro wà nínú è...Àwọn ìlú wo ni a mọ̀n pẹ̀lú iyán jíjẹ tí wón si mọ iyán gún jù?
09/17/2021

Iyán funfun àti ọbẹ̀ Ẹ̀fọ́ Rírò tí irú wooro wà nínú è...

Àwọn ìlú wo ni a mọ̀n pẹ̀lú iyán jíjẹ tí wón si mọ iyán gún jù?

Àmàlà tàbí Ọkà, èwo nínú àwọn orúkọ yìí ni èyin mo oúnjẹ yìí sí.
09/16/2021

Àmàlà tàbí Ọkà, èwo nínú àwọn orúkọ yìí ni èyin mo oúnjẹ yìí sí.

Bawo ni a ṣe nki Alaboyun n'ilẹ Yoruba??
09/16/2021

Bawo ni a ṣe nki Alaboyun n'ilẹ Yoruba??

Ẹ FURA ÒÒÒAyédèrú epo Pupa tí wá lọja bayi òòòLátàrí bí gbogbo nkan ṣe gbowó lórí lásìkò yí, àwọn ẹni ibi ẹ̀dá tí kò àwọ...
08/23/2021

Ẹ FURA ÒÒÒ

Ayédèrú epo Pupa tí wá lọja bayi òòò
Látàrí bí gbogbo nkan ṣe gbowó lórí lásìkò yí, àwọn ẹni ibi ẹ̀dá tí kò àwọn èpò Pupa tí wọ́n tí po papọ mọ ọda tí ọjọ́ tí lọ lórí ẹ ti wọn si n ta ni edinwo. Ẹ gbìyànjú kí ẹ yẹ epo Pupa tí ẹ bá ra lọja wo dáadáa kí ẹ tó fi ṣe ọbẹ̀ òòò.
Kí Ọlọ́run Ọba kò má fi ísọ rẹ sọ wá lorile-ede yí ni òòò àmín

Gbìyànjú láti share eto yí sì ọ̀pọ̀lọpọ̀ group. A ó ní je nkan tó má rán wa lọ sọrun àpàpàǹdodo àmín.

08/21/2021
08/10/2021
08/07/2021
08/06/2021

Itan Ogedengbe Agbogungboro Ara Awon Akoni Ile oduduwa

Akinkanju Balogun ni Saraibi Ogedengbe to tun jẹ Obanla ilu Ijesha (Oba-Ala Ogedengbe ti Ileṣa Kinni).

Wọn a maa pe e ni alajẹ Ogedengbe Agbogungboro.

Ilu Atorin ni Ilesha, ipinlẹ Oṣun ni Eleduwa ti fi Ogedengbe ta awọn obi rẹ alagba Apasanforijiwa ati iyaafin Falupo lọrẹ.

Ilu yii ko ju iwọn ogun kilomita lọ si Ileṣa tii ṣe ilu iya rẹ.
Oke Oriṣa ni ilu baba rẹ eyi ti ko fi bẹẹ jinna ju bi Atorin naa ṣe ri si Ileṣa lọ ti wọn si jọ wa ni ijọba ibilẹ kan naa, Atakomosa East Local Government Area.

Awokọṣe rere ti oun funra rẹ di itan to si tun gbe aṣa ga lati igba ewe rẹ t**i to fi wọ kaa ilẹ ni Ogedengbe.

Ọmọ Ijeṣa ni ere - Ogedengbe gboya ninu ilu rẹ o si ni ifẹ aiṣẹtan fun awọn ara ilu Ijeṣa bi o tilẹ jẹ pe o jẹ ẹnikan ti ko gba igbakugba ti ko si bẹru ẹnikẹni.

Igbakuugba ti ogun ba de, ile logun ba a tori gudugudu ni ko figba kan turaa lẹ lati doju ija kọ ẹnikẹni to ba tọja rẹ kii sii kaarẹ afi to ba bori ija naa.

Ẹni ti gbogbo ọkunrin fẹ ba dọrẹ ni bẹẹ si ni bi obinrin ko o lọna, wọn a ni beleyi o jẹ ọkọ ẹni ṣebi a ṣi jẹ ale ẹni.

Ìbí àti dídàgbà Ogedengbe:
Ohun to wu ni lori ninu itan akinkanju yii ni wi pe ki wọn to bi i ni Ifa ti fọhun pe oun ni yoo jẹ olugbala ilu Ijeṣa.

Wọn bi i bi wọn ṣe n bi gbogbo ọmọ to ku to si dagba gẹgẹ bi ọdọ to ja fafa ninu iṣẹ ṣiṣe.
Eyi fi han pe o jẹ alagbara ọmọ to si tayọ awọn ẹlẹgbẹ ni gbogbo ọna.

Bi wọn ba jọ wọya ija, afi ko fẹyin wọn janlẹ ni gbogbo igba - eyi lo bi orukọ OGEDENGBE ti wọn fun un tori orukọ abisọ rẹ gan ni Saraibi.
Nigba to dagba, Ogedengbe doju ọpọ ifẹhonu ija han kọ awọn ara Ibadan ti wọn n fiya jẹ awọn ara Ijeṣa.

Lasiko kan ninu ifẹhonu ija han yii ni wọn ra a mu ti wọn si gbe e lọ Ibadan.
Kii ṣe ẹni to kọla tẹlẹ, lataari eyi lawọn ara Ibadan bu ila si oju rẹ ki wọn to tu u silẹ.

Ninu ikọ ogun ilu Ibadan, Ogedengbe ja fitafita t**i to fi di Ọgagun o si wa pada lati lọ dari ikọ ogun ti ilu Ijeṣa.

Ogun Jija Ogedengbe:
Lẹyin eyi, o ko ọpọlọpọ ọmọ ogun to pọ jọ ti wọn si doju ija kọ ilu Ibadan lọpọlọpọ igba.

Kii ṣe Ibadan nikan, o tun ba iṣẹ ogun jija rẹ de Ekiti, Akoko nibi to ti ta ọpọ wọn lẹru leyii fi jade ninu oriki rẹ pe "O ṣọkọ Ekiti ṣọkọ Akoko".
Koda o tun gbe iṣẹ ogun jija rẹ ipinlẹ ti o n jẹ Edo lonii.

Ṣe ni Ọba ilu Benin ni lati tu u loju pẹlu ọpọlọpọ ilẹkẹ, ẹru, atawọn ohun pataki miiran pe ko ma gbe ogun de ọdọ awọn eeyan oun.
Lẹyin eyi lo pada si ilu Igbara Oke lati tẹdo sibẹ. asiko yii kan naa ni awọn ara Ibadan tun dide ogun ti Ogedengbe si gba lati jẹ Balogun Ijeṣa ati Ekiti lati koju ilu Ibadan.

Ija yii le gan an to bẹẹ to to ọdun mẹsan an ko to dawọ duro.
Ọgagun Bower to jẹ Kọmiṣọnna Ọlọpaa ilu Ibadan nigba naa lọhun lo pari aawọ ogun yii lọdun 1886.

Gbogbo iwa akinkanju yii lo sọ Ogedengbe di akọni niluu rẹ to si fi di ọkan lara awọn ọkunrin to pataki ju lọ ni ilẹ Yoruba, orilẹ-ede Naijiria ati ilẹ Afirika.

Eyi ri bẹẹ nitori kii ṣe awọn ilu mẹrin taa ti darukọ yii nikan ti Ogedengbe ti jẹ gbajugbaja.
Ko da, o kan Ife, Ilorin to fi di wi pe ọta wa pọ to fẹ doju ija kọ ilu Ibadan.

Ogun ti Ekiti-parapọ gan an waye lẹyin ti wọn jagun ṣẹgun ogun Kiriji miran laarin ọdun 1877 - 1892. Ogun nla ni Ogun Kiriji jẹ ninu itan Yoruba.

Lati jẹ ki awọn ilu to parapọ lati jẹ ọwọ ogun kan naa wọ ara wọn daadaa,
Ogedengbe fẹ iyawo kaakiri gbogbo ibi to ti lọ jagun.

Itan sọ pe o le ni iyawo mọkandinlọgọrun ti Ogedengbe fẹ kaakiri ilẹ Yoruba.
Itan kan tun sọ wi pe lasiko ogun kan, wọn bẹ Ogedengbe lori ṣugbọn o fi agba han iku bẹẹ si ni ara rẹ rin lọ lati gbe ori rẹ pada to si gbe e le ọrun ara rẹ.

Eyi mu ki awọn ọta rẹ tubọ maa wariri fun un tori wọn wo o pe ki wa lo lee pa Ogedengbe bi bibẹ lori ko ba lee ran an lọ salakeji.
Ọrọ pọ ninu iwe kọbọ nipa Ogedengbe Agbogungboro, ko si ṣe sọ tan nitori akọni ti ko ṣee gbagbe ni nilẹ kaarọ o jiire ni.

T**i di oni, ami idanimọ to wa niwaju ile Ogedengbe ni ida lati ran ni leti asiko jijẹ akọni ti wọn bẹẹ lori to si tun ye e.

08/05/2021
Akoni omoyele sowore
08/05/2021

Akoni omoyele sowore

08/05/2021

Iroyin lati enu akoni awikoko

08/05/2021

Iro ayo lati enu akoni

Se iwo mon baba wa AKONI yi
08/04/2021

Se iwo mon baba wa AKONI yi

Address

New York
New York, NY
10007

Telephone

+19292000063

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Awon AKONI yoruba posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Videos


Other Media/News Companies in New York

Show All

Comments

The giant of West.you are great.
x

Other Media/News Companies in New York (show all)

Dévelopage Info Plus Bajo El Lente De Lydia Susana Holiday Fix DD News 360 Fernando Live News Nway Oo News HipHop50 Public Ke Aawaz Junior waxy Arun Patel walter schupfer management Dipangkar rabha hrithik Kahramanmaraş Haber ve Yol Durumu Teluk Batang Update Deenul Haque